Five G: Ìjọba àpapọ̀, ẹ so ifilọlẹ ẹ̀rọ alatagba 5G rọ na - ilé asofin àgbà

5G

Oríṣun àwòrán, others

Ilé asofin àgbà ilẹ̀ wa ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti so ifilọlẹ ẹ̀rọ alatagba itakun àgbáyé 5G rọ̀ ná.

Ilé asofin àgbà pàrọwà yìí lásìkò ìjíròrò lórí abá kan, tí asofin Uche Ekwunife gbé wa ṣíwájú ilé, èyí tó fi ń pe àkíyèsí àwọn asofin àgbà si ipo ti ifilọlẹ ẹ̀rọ 5G náà dé dúró.

Sẹnatọ Ekwunife ni, òun gbé àbá ọhun wá síwájú ilé, láti rọ ìjọba àpapọ̀ pé kò sún ifilọlẹ ẹ̀rọ alatagba 5G ọhun síwájú títí tí yóò fi parí ìwádìí rẹ, lọ́nà àti fi dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú pé, ààbò tó péye wà fún wọn.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ ààrùn ni coronavirus bí?

Nígbà tó ń dá si ìjíròrò náà, igbakeji olórí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó pọ̀ julọ, Sẹnatọ Ajayi Boroffice ni ifilọlẹ ẹ̀rọ alatagba 5G náà, tí ń mú awuyewuye tó pọ̀ lọ́wọ́.

5G

Oríṣun àwòrán, others

O ni yóò dáa kí ìjọba gba àwọn èèyàn tó mọ nípa ẹ̀rọ alatagba naa láàyè láti jíròrò lórí ire àti ibi tó wà nínú ẹrọ itakun agbaye náà.

5G

Oríṣun àwòrán, others

Nínú ọ̀rọ̀ tíẹ, Sẹnatọ Opeyemi Bamidele ni, ìjọba tí kò bá mọ ojuse rẹ ni isẹ, ní yóò máa tẹ́wọ́gba àmúlò ẹ̀rọ ìgbàlódé tó léwu fún àwọn araalu.

Àkọlé fídíò, Kínni ààrùn coronavirus nííṣe pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ 5G?

O ni kò sí ileesẹ ìjọba kankan tó tíì ṣe ìwádìí imọ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rọ alatagba 5G náà, kò tó di pé a ń ṣe ifilọlẹ rẹ.

5G

Oríṣun àwòrán, others

Ilé asofin àgbà tí wá rọ àwọn igbimọ ilé to wà feto ibaraẹnisọrọ, ìmọ̀ sayẹnsi, ẹ̀rọ itakun àgbáyé pẹ̀lú eto ìlera láti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí lórí ẹ̀rọ alatagba 5G, ká lee mọ àǹfààní àbí àléébù ẹ̀rọ alatagba náà