Lockdown Extension: Kí ló le mú kí ìjọba Nàìjíríà ó dá òfin ìṣéde padà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ọsẹ akọkọ ti ijọba dẹ ofin konile o gbele ṣe n wa sopin, ni ọpọ araalu, paapa lori ayelujara ti n sọ pe ki ijọba o tun gbe ofin konile o gble jade pada.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun ni anfaani jijade yẹ ko pari.
Ni eerro awọn kan, wọn le sọ pe anfaani pupọ ni bi ijọba ṣe gbẹsẹ kuro lori ofin konile o gbele nitori pe awsn eeyan raaye jade lọ si ẹnu'ṣẹ wọn lati pawo. Awọn miran si n sọ pe ominuu n kọ awọn pe eyi yoo mu ki awọn to ni coronavirus ko pọ si ni Naijiria.
Awọn kan tiẹ gbagbọ pe ti ijọba ba tun ṣe ofin konile o gbele, ọrọ aje yoo dẹnukọlẹ.
Laarin ọjọ kẹrin, oṣu Karun si ọjọ kẹjọ, oṣu Karun, awọn to ni aarun naa ti kuro ni 2558 to wa si 3526, nitori pe o ti n tan kalẹ laarin adugbo.

Kinni eero awọn ọmọ Naijriia lori ipadabọ konile-o-gbele?
Ori ayelujara ni ọpọ ọmọ Naijria ti n sọ erongba wọn lori ṣiṣe ofin konile-o-gbele miran, paapa ni ipinlẹ Eko ti aarun naa pọ si julọ.
Ṣugbọn ṣa, minisita fun eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire sọ fun BBC pe ọwọ araalu ni ọna abayọ wa, to fi mọ awọn olori ẹsin ati ileeṣẹ iroyin, lati maa la awsn eeyan lọyẹ pe fun anfaani ara wọn ni ofin ijọba.
Bakan naa ni Dokita Ehanire sọ pe "ti awọn eniyan ba mu ilo ibomu-bẹnu, yiyago fun'ra ẹni lawujọ, ni koko, yoo fun wa ni esi ti a n fẹ".
Minisita naa sọ pe ọwọ Aarẹ Buhari lo wa lati kede konile-o-gbele miran, lẹyin ti wọn ba ṣe agbeyẹwo gbigbẹsẹ kuro lori ofin naa lẹyin ọsẹ meji, ki wọn tun to mọ nkan to ku lati sẹ.
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita onimọ iṣegun oyinbo ni Naijiria, Dayo Duyile sọ fun BBC pe ẹgbẹ naa sọ fun ijọba pe ko ti to asiko to yẹ ki wsn dẹ ofin konile-o-gble nitori pe ko si nkankan to fihan pe Naijiria ti n bori aarun naa.
O sọ a ni lati pawọpọ dẹkun aarun coronavirus ni Naijiria.
Lori pe boya ijọba n fi ọrọ lọ wọn ko to o gbe igbesẹ, Duyile sọ pe ijọba kii ṣaba pe wọn, ṣugbọn awọn n ba wọn sọ ni idakọnkọ, ti wsn le tẹle tabi kọ imọran naa.
Lori bi awọn eeyan kan ṣe n beere pe ki ijọba o da ofin konile-o-gbele pada, Dokita Duyile sọ pe kii ṣe ofin konile-o-gbele nikan lo le dẹkun itankalẹ aarun yii. O ni ijọba gbọdọ jẹ ki awọn to n ṣayẹwo fun pọ si ju bo ṣe n ṣe lọwọlọwọ.
O ni mejeeji yoo ran ara wọn lọwọ lati kapa aarun naa.

Ogun Doctor's Strike: Ẹgbẹ́ dókíta ló ra ìbòmú fúnra wa- Alága NMA Ogun
Lánàá òde yìí ni àwọn dókíta ilé ìwòsàn ìkọ́ni Olabisi Onabanjọ (OOUTH) Sagamu ní àwọn yóò dásẹ́ kalẹ̀ fún ọjọ mẹ́ta láti kilọ fun ìjọba lórí àwọn ìbéèrè tó wà níwáju wọ́n láti ọjọ́ pípẹ́.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló rò pé kìí ṣe àsìkò to tọ̀nà rèé fún yansẹlódì ti ilé ìwòsàn ìkọ́ni yìí gùnlé.
Lásìkò ti BBC News Yoruba ba alága NMA ní ìpínlẹ̀ Ogun náà sọ̀rọ̀ Dókítà Lawal Akinlade láti mọ ìdí ti irú ìgbésẹ̀ yìí fi wáyé ni àsìkò yìí tí gbogbo àgbáye n koju ààrun Corornavirus
Dókítà Akinlade ni ọ̀rọ̀ to fa ìyásẹlódi ránpẹ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ òní, sùgbọ́n èyí tó lágbára jùlọ níbẹ̀ ni pé, ko si àwọn èròjà ìdáàbò bo ara ẹni (PPE) tó kójú òṣùwọ̀n láti koju ààrùn Corornavirus.
Akinlade ni èyí lo jẹ́ ki àwọn òṣìṣẹ́ ilera pa ọkan pọ láti lọ fún ìyanṣẹ́lódì yìí,
O fi kun un pé láti bii ọdún díẹ̀ sẹyin ni àwọn oṣìṣẹ́ náà ti s ọfun ìjọba nipa owo oṣù ti ko dọgba láàrin awọn ilé iwosan ikọni miran láwọn ìpínlẹ̀ to kù àti ilé iwosan ìkọ́ni ti ìjọba àpapọ̀.
Akinlade ni ibi ti ọ̀rọ̀ náà lágbára dé, àwọn ẹgbẹ́ dókìta ló dáwó láti ra ìbòmú ti wọn fẹ́ pin fun àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó kù
"Pálí ìbòmú ńla méjì ti a rà, owó rẹ̀ to mílíọnù kan náírà."
"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn wa yóò ti maa ṣe ìtójú aláìsàn láìmọ̀ pé wọ́n ni ààrùn Corornvirus, kò yẹ ki a maa fi iná sórí òrùlé sùn"
Ní bayii àwọn míràn ti lọ ya arawọn sọ́tọ lẹ́yìn ti wọ́n ti ni nkan ṣe pẹ̀lú alaarun Covid-19 lai lo aṣọ ààbò.
O ní bi aṣé n sọ̀rọ̀ yìí kò si àwọn èròjà ìdáàbò ara ẹni to káári, bótilẹ̀ jẹ́ pé ìyaṣẹ́lódì yìí kò kan àwọn dókítà to n mójuto àwọn aláàrùn Covid-19.
Akinlade fi kun un pé, inú ìyanṣẹ́lódi ni àwọn wà nígba ti gómínà Dapo Abiodun gorí oye sùgbọ́n aàwọn ṣẹ́wẹ́le ni láti ṣe àpọ́nlé fún, síbẹ̀ ko si igbéṣẹ̀ kankan to gbe lóri ọ̀rọ̀ náà láti igba to ti gori oye.
Nígbà ti BBC pé Kọmísọ́nà ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Ogun dókítà Tomi Coker sàlàye pé, o ti yá ju lásìkò yìí láti sọ ìgbẹ́sẹ̀ tí ìjọba yóò gbé, sùgbọ́n ìjọba ti n ba olóri wọ́n sọ̀rọ̀ láti wa ojúùtú si ìṣòrò to wà nílẹ̀.















