Aṣọ òkè: Alákọ̀wé ní ọ̀nà láti wá oúnjẹ fáwọn tó ń ṣe aṣọ òkè ló ṣún òun débẹ̀
Tunde Owolabi, tii se onisowo to n fi asọ oke se baagi ati bata salaye fun BBC Yoruba pe, lẹyin ti oun fẹyinti lẹnu isẹ lọdun marun sẹyin ni oun bẹrẹ isẹ naa.
Owolabi ni bata kan ti oun ni nile, lo fun oun ni ọgbọn inu pe, oun lee lo asọ oke lati fi se baagi ati bata.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa ‘Ajala Travels’?
- Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde
- 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
- Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
O ni oun roun pe, ki ni ọna ti oun lee gba se iranwọ fawọn eeyan to n se asọ oke, ti ebi ko fi ni pa wọn, ti ko ba si igbeyawo tabi oku sise, ni oun se bẹrẹ isẹ yii.
Owolabi tun fidi rẹ mulẹ pe, okoowo naa ti n ni agbega lati ọdun mẹrin ti oun ti daa silẹ.