Sex for Grades: Olùkọ́ méjì tí ìròyìn BBC tú láṣìírí lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ lọlé

Ile ẹkọ giga fasiti orilẹede Ghana ti jawe lọ rọọkun nile fawọn olukọ meji tẹsun lọ mọ lẹsẹ ninu fidio iroyin BBC to tu aṣiri awọn olukọ fasiti to fi ibalopọ halẹ mọ awọn akẹkọọ tori maaki.
Awọn alaṣẹ fasiti naa ni ile iwe awọn ti ri fidio BBC naa bẹẹ si ni awọn ko foju kere ọrọ to ba ni ṣe pẹlu fifi ibalopọ halẹ mọ akẹkọọ awọn si koro oju si i.
Nitori eyi, "igbimọ alaṣẹ fasiti ti gbe igbesẹ lati le olukọ mejeji, Ọjọgbọn Ransford Gyampo ati Ọmọwe Paul kwame Butakor ti wọn wa ninu fidio naa lọ sile".
Awọn alaṣẹ fasiti Ghana ṣe eyi lati faye gba iwadii kikun lori ẹsun naa.
Ṣaaju ni fasiti keji ni orilẹede Naijiria ti olukọ wọn naa han ninu fidio ọhun fun ẹsun ibalopọ ti gbe igbesẹ yii bakan naa ni kete ti iroyin ọhun ti de ọdọ alaṣẹ tiwọn.
Ọjọ keje oṣu kẹwaa dun 2019 ni fidio naa jade latọwọ ẹka BBC Africa Eye ti ile iṣẹ BBC.









