Sex For Grades: Four Square Church tí ní kí olùkọ́ fásitì Pasitọ̀ Boniface lọ fìdímọ́lé

unilag

Oríṣun àwòrán, @unilag

Àkọlé àwòrán, UNILAG ko fọwọ si iwa ibajẹ biba akẹkọọ sun nitori maaki rara.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àwọn aláṣẹ fásitì Eko ninu atẹjade ti ti kéde pé ki Omowe Boniface lọ rọọ́kún nílé ná

Fasiti Eko kede pe Ọmọwe Boniface ko gbọdọ lọ si agbegbe ikọwe ni fasiti naa lẹyin ipade pajawiri ti wọn ṣe.

Lẹyin ti ile iṣẹ BBC gbe iwadii wọn sita lori awọn olukọ kan nile iwe giga iwọ oorun ilẹ Adulawọ ti wọn n beere fun ibalopọ ṣaaju maaki ni oriṣiiriṣii nkan ti n ṣẹlẹ.

Iṣẹ iwadii BBC yii ṣafihan olukọ ni fasiti ijọba apapọ ni Eko ati ni Ghana ni eyi to ti n tu aṣiri oriṣiiriṣii sita bayii,

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Fasiti Eko to gba Omowe Boniface Igbeneghu to n kọ awọn akẹkọọ nipa ede ajoji tilẹ Yuroopu ni fasiti naa ti ni ko ṣiwọ iṣẹ na.

Kete ti fidio BBC yii n ja nilẹ ni awọn alaṣẹ Fasiti Eko ti pe ipade pajawiri lori ọmọwe Boniface.

Lẹyin ti ọpọ nkan ti n ṣẹlẹ lẹyin ti iwadii BBC yii jade ni fasiti Eko ni wọn ti ni ki Boniface lọ rọọkun nile naa titi awọn yoo fi pari iwadii wọn lori ọrọ yii.

Boniface yii ni awọn ọmọ igbmọ ni fasiti UNILAG yoo ṣe iwadii to yẹ lori ẹsun fidio naa ki fasiti Eko to mọ ohun to kan.

Fasiti Eko mẹnuba awọn ilana ofin ileewe giga naa lori ibalopọ ati iwa aitọ laarin akẹkọọ ati olukọ.

Fasiti Eko ni gbogbo olukọ ti ade iwadii BBC ba si mọ lori lo maa foju wina ijiya to tọ.

Bakan naa ni fasiti yii ṣeleri lati rii pe ọkan awọn akẹkọọ wọn balẹ pẹlu fifi iya to tọ jẹ awọn ti akẹkọọ ba fẹsun kan ti iwadii si fidiẹ mulẹ.

oro alaṣẹ UNILAG

Oríṣun àwòrán, @unilag

Àkọlé àwòrán, Koda UNILAG ti iyara Cold Room pa lẹyin fidio BBC

Odindin ọdun kan ni BBC fi ṣe iṣẹ iwadii yii to ṣafihan iwa buruku awọn olukọ kọọkan ni fasiti iwọ oorun ilẹ Adulawọ yii.

Bakan naa ni awọn alaṣẹ ijọ Olorun Four Square ti ọmọwe Boniface ti n jọsin naa kede pe ko dẹkun gigun pẹpẹ iwaasu titi iwadii wọn yoo fi pari.

Igbesẹ wo ni ijọ Four Square ti gbe lori iṣẹlẹ yii?

Four Square Church tí ní kí olùkọ́ fásitì Eko, Pasitọ̀ Boniface, lọ fìdímọ́lé.

Ile ijọsin naa ni awọn gbe igbesẹ yi lati le sẹ iwadii ẹkunrẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan olukọ fasiti naa.

Ile ijọsin Four Square Gospel Church Nigeria ti paṣẹ ki Pasito Boniface Igbenoghu lo fidi mọle titi ti awọn yoo fi pari iwadii lori rẹ.

Aworan olukọ Boniface
Àkọlé àwòrán, Four Square Church tí ní kí olùkọ́ fásitì Eko, Pasitọ̀ Boniface, lọ fìdímọ́lé.

Igbesẹ yi ko ṣẹyin iroyin iwadii kan ti ile iṣẹ BBC gbe jade lori ifipabanilopo lati le fi gba maaki eleyi to ṣafihan Pasito Boniface nibi ti o ti n hu iwa aitọ si akẹkọbinrin kan.

Loju opo Twitter ati Facebook ile ijọsin naa ni wọn fi atẹjade si eleyi ti Rev. Ikechukwu Ugbaja fi ọwọ si.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ninu atẹjade naa, ile ijọsin naa ni awọn ko ''faaye gba iru iwa buruku bayi ati pe awọn ko lọwọ si iru iwa ti Pasitọ Boniface hu yi''

ilede

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Four Square sọrọ lori olukọ fasityi Eko pe...

Wọn tẹsiwaju pe ''A o gbe igbesẹ to ba yẹ lori ọrọ yii nigba ti a ba pari iwadii wa".

Ki o to di igba naa, a ti paṣẹ pasitọ ti ọrọ yi kan ki o maṣe kopa ninu iwaasu kankan."

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Foursquare Gospel Church

Àkọlé àwòrán, Oludari ile ijosin Four Square Gospel Church

Ẹwẹ, awọn akẹkọọ ni fasiti ilu Eko ti o ba BBC sọrọ lawọn ko tii foju kan olukọ naa lẹyin ti BBC gbe fọnran fidio naa jade lọjọ Aje.

Boniface
Àkọlé àwòrán, Ọjọ gbogbo ni t'ole..... iṣẹ olukọ ko yẹ ko mu iwa ibajẹ bayii dani

Ki lawọn eeyan n sọ nipa iṣẹlẹ yi?

Igbagbọ awọn obi ati alagbatọ to ran akẹkọọ lọ sile iwe ni ki wọn lọ kawe, ki wọn si di eeyan lọjọ ola.

Laye atijọ olukọ dabi obi ati alagbatọ fawọn akẹkọọ, ṣugbọn nkan ti yipada lasiko yii nile ẹkọ giga gbogbo.

Ọpọ awọn olukọ lo ti n jẹ koriko abẹ wọn, ti wọn n huwa aitọ nipa biba awọn akẹkọọ sun.

Lẹyin ti ileeṣẹ BBC gbe iwadii wọn jade to ṣafihan olukọ fasiti Eko, ati ti fasiti Ghana, to n beere ibalopọ̀ lsna aitọ, ni awọn eniyan ti n fi ero ọkan wọn han lori ayelujara.

Ẹkunrẹrẹ iwadii naa ni yii:

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Ni oju opo BBC New Yoruba ni Facebook, ọpọ ló n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa ti awọn olukọ yii hu nitori pe ko bojumu rara ati pe o ṣeni laanu pe ọpọ awọn olukọ to mọṣẹ olukọ daadaa lo n huwa yii.

Ero awọ̀n eeyan lori olukọ to n beere ibalopọ lọwọ akẹkọọ lọna aitọ

Iwa buruku yii ko jẹ tuntun loju awọn eniyan mọ nitori ọpọ agbalagba olukọ lade iwa ibajẹ yii ti ṣimọ lori ‘Lóòótọ́ ni ọ̀jọ̀gbọ́n fẹ́ bá mi lòpọ̀’.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Fásitì OAU ní ohùn ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele ni wọ́n ká sílẹ̀

Awọn miran ni ki ileeṣẹ BBC wa si ile iwe awọn kaakiri Naijiria nitori o ti di ankoo fawẹli to n ba ni ninujẹ:

Ero awọ̀n eeyan lori olukọ to n beere ibalopọ lọwọ akẹkọọ lọna aitọ

Ohun to jọ ọpọ eeyan loju, to si n bi wọn ninu julọ, ni ọjọ ori ẹni ọdun metadinlogun ti ọrọ naa kan, eyi buru jai.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo gboriyin fun ileeṣẹ BBC fun iṣẹ ọpọlọ to n fọ awujọ mọ tó n jade lagbalaBBC nigba gbogbo:

Ero awọ̀n eeyan lori olukọ to n beere ibalopọ lọwọ akẹkọọ lọna aitọ

Awọn ọmọ Naijiria miran ni ki ijọba gbe igbesẹ to yẹ lati wagbo dẹkun fawọn olukọ to n huwa ibajẹ yii ki ọkan awọn akẹkọọ le balẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Godson mẹnuba iwaasu Baba Adeboye ti ijọ RCCG to fi sọrọ lori ibalopọ awọn olukọ ni fasiti lasiko to yi n ṣiṣẹ olukọ.

Iyiosa gba pe iwa yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ bikoṣe pe ki onikaluku ṣetan lati fopin sii bayii:

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Eghosa naa sọrọ lori iriri rẹ lọdun 2015 ni fasiti Eko bi olukọ kan ṣe féèlì akẹkọọ kan lẹẹmeji nitori pe o fẹ baa sun pe idajọ Olorun lo de loju rẹ:

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Ọpọ ọdọ kilọ iwa ibajẹ yii larin awọn obi pe ki wọn yee mu itiju ba awọn ọmọ wọn nitori ti aṣiri ba tu tan, tẹbi tara ni itiju yii a kàn.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6