Ìfipábánilòpọ̀: Ọlọ́pàá ní ọkùnrin tó fipá bá ọmọ ilé ìwé UNILAG lò, tún jí pátá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Se ni awọn eeyan yanu sile, lai lee pa de nile ẹjọ to n gbọ awọn akanse ẹsun, nigba ti ẹjọ kan afurasi kan ti wọn lo fipa ba ọmọ ile iwe fasiti UNILAG meji lo pọ.
Nkem Ejelonu, to jẹ ọlọpaa to ṣe iwadi ọrọ naa, nigba ti ọmọbinrin naa lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa, tun salaye pe, John Otema, tii se olujẹjọ, tilẹ tun ji pata ọmọbinrin naa lọ.
Oṣu kini ọdun 2018 ni Ejelonu sọ fun ile ẹjọ wipe, Otema lu ọmọbinrin naa ni alubole, o fun-un lọrun, o tun ge jẹ nigba to fipa ba ọmọbinrin naa lo pọ ninu ọgba fasiti naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn ko pọ ju fun afipabanilopọ'
- Ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀: Orí Twitter ló ti bẹ̀rẹ̀, ikú ló já sí
- Wọn dajọ iku mẹrin f'ẹni f'ipa b'ọmọde lo
- Ìbò 1.6m ni mo fi borí Buhari, ojú òpó INEC gan leè jẹ́rì si - Atiku
- Owó dé! Ilé Aṣòfin Àgbà fòǹtẹ̀ lu N30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́
- A gba ìwé ìpẹ̀jọ́ ₦200m lọdọ mọlẹbi Sugar - UCH
Ko pẹ lẹyin rẹ ni wọn sọ pe afurasi naa tun ba ọmọbinrin keji lo pọ.
Ejelonu ni, oun ti lọ wa pata ati kọmu ọmọbinrin naa nibi ti Otema ti fipa baa lo, ṣugbọn nigba ti oun ko ri wọn nibẹ, oun tun lọ wa ile afurasi naa ni Bariga, Ṣugbọn ko ri pata naa nibẹ pẹlu.
Adajọ Abiola Soladoye ti sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹsan-an oṣu karun-un ọdun 2019, ti igbẹjọ yoo si tẹ siwaju.









