Election 2019 Updates: Atiku ní ìbò 18m ni mo ní, Buhari sì ní ìbò 16.5m

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Facebook/Atiku Abubakar

Àkọlé àwòrán, Ẹto idibo aarẹ

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar sọ pe, ẹrọ kọmputa ajọ eleto idibo INEC fihan pe ibo to le ni miliọnu kan aabọ, l'oun fi bori aarẹ Muhammadu Buhari, to n soju ẹgbẹ oselu APC ninu idibo aarẹ to lọ.

Ọjọ Aje ni Atiku morile ile ẹjọ lati gbe atako rẹ kalẹ, nigba to ku wakati mẹrinlelogun pere ki iye ọjọ ti ofin la kalẹ fun oludije kan lati pe ẹjọ tako esi ibo pe.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji to lọ ni ajọ INEC kede pe, aarẹ Buhari lo jawe olubori ninu ibo aarẹ pẹlu ibo to le ni miliọnu mẹẹdogun, ti Atiku si se ipo keji pẹlu ibo miliọnu mejila o le diẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn Atiku ati ẹgbẹ PDP, ti wọn jẹ olupẹjọ ni, magomago wa ninu esi idibo ti ajọ INEC kede naa.

Awọn olupẹjọ fidi rẹ mulẹ fun igbimọ olugbẹjọ ibo aarẹ naa pe, ẹrọ kọmputa ajọ INEC fihan pe, Atiku lo leke pẹlu ibo to le ni miliọnu mejidinlogun ti aarẹ Buhari si ṣe ipo keji pẹlu ibo to leni miliọnu merindinlogun ati aabọ.

Àkọlé fídíò, Demilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé

Wọn ni iye ibo ti Atiku ati Buhari ri niyi ni ipinlẹ marunlelọgbọn nitori ko tii si esi idibo aarẹ ti ipinlẹ Rivers lori ẹrọ kọmputa INEC, lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keji.