Building Collapse: 'Àjọ wa kìí ṣe àjọ wóléwólé, àwọn èàyàn lóò fá'

Ile mii to wo lu lẹ
Àkọlé àwòrán, Ile miran tun wo l'Eko

Adari ajọ to n ri si ọrọ ile kikọ nipinlẹ Eko, LASBCA Ọgbẹni Lekan Ṣhodẹinde sọ pe ọpọ ile ko ba ti di wiwo ti awọn onile ba tẹle ilana ajọ LASBCA nipinlẹ naa.

Shodẹinde to ba BBC Yoruba sọrọ lori ile to ya lulẹ lagbegbe Oke Aarin, Lagos Island, sọ pe o ṣeni laanu pe ọpọ onile lo maa n kọ eti ikun si ijọba lori ofin ti ijọba la kalẹ lori ile kikọ nipinlẹ Eko.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, LASBCA sọ̀rọ̀ lórí ilé wíwó

O ni ile iṣẹ LASBCA kii ṣe ile iṣẹ wole wole, o ni aitẹle ofin ijọba lori ile kikọ lo jẹ ki ajọ LASBCA maa wo awọn ile ti ko dangajia.

Àkọlé fídíò, Àlàyé rèé lórí ilé kẹ̀ta tó wó l'Eko

Ọgbẹni Shodẹinde fikun ọrọ rẹ pe nigba miran o le jẹ pe owo diẹ ni onile ni lati na sori ile ṣugbọn ọpọ onile kii fẹ tẹle ilana ajọ LASBCA.

Ninu alaye rẹ, ọga ajọ LASBCA sọ pe akọkọ ninu ilana ajọ naa ni pe ti awọn ba ṣakiyesi wi pe ile kan ko duro daadaa ti o si le ṣakoba fawọn to n gbe inu rẹ, ajọ LASBCA yoo fun onile niwe lati sọ fun wọn pe ile naa yoo wo.

Ile mii to wo lu lẹ
Àkọlé àwòrán, Ile to tun wo l'Eko

O ni lẹyin naa ni ajọ LASBCA yoo ṣayẹwo lọna sayẹnsi (Structural Test) lati mọ bo ya ile naa le gba atunṣe tabi ko le gba a.

Ọgbẹni Shodẹinde sọ pe o di dandan ki onile tun ilẹ ṣe ti ayẹwo ba fihan pe ile naa nilo atunṣe, bẹẹ lo fidi rẹ mulẹ pe gbogbo ile ti ajọ LASBCA ba fawọn onile niwe le lori kọ lo maa n di wiwo.

Ọga ajọ LASBCA ni onile to ba gbawe ayẹwo lati ọdọ awọn ti ko ba ṣe e, awọn yoo fun un ni iwe keji ti wọn n pe ni ''Quit Notice'' pe ki gbogbo awọn to wa ninu ile le ko jade.

Ile mii to wo lu lẹ
Àkọlé àwòrán, Ki ile naa to ya lu lẹ

Lẹyin naa ni ajọ LASBCA yoo ti ile naa pa, ti wọn yoo kan si onile lati mu iwe ayẹwo aridaju pe ile naa si duro deedee.

O ni ijọba maa wo ile naa ti onile ko ba gbe igbesẹ lati tun ile ọhun ṣe.

O ni ojuṣe awọn onile ni lati maa ṣe atunṣe ile lati igba de igba ati pe onile gbọdọ maa ṣayẹwo ile loreekoree.

Ọgbẹni Shodẹinde ni awọn ayalegbe gbọdọ rii pe iwe ẹri ijọba wa lori ile ti wọn ba fẹ gba ki wọn to gba a.

Ile mii to wo lu lẹ
Àkọlé àwòrán, Ile miran wo L'Eko

Ọga ajọ LASBCA tun ni ojuṣe awọn ara adugbo ni lati tawọn lolobo ti wọn ba ri ile kan ti ko ba duro daadaa.

O ni awọn eeyan le pe ajọ LASBCA lori awọn nọmba yii- 07000537222 tabi 07000050504040 ti wọn ba fẹ tawọn lolobo lori ile ti ko ba duro daadaa.