Ikú Suga: UCH ní àwọn agbẹjọ́rò òun yóò fèsì fún mọ̀lẹ́bí Sugar

Temitope Olatoye

Oríṣun àwòrán, Temitope Sugar

Ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun yunifasiti Ibadan, UCH, ti sọ fun BBC Yoruba pe, oun yoo fesi to tọ si iwe ipẹjọ ti mọlẹbi ilumọka oloṣelu Temitope Olatoye 'Sugar' fi sọwọ si oun.

Agbẹjọro mọlẹbi oloogbe naa lo ti kọkọ kowe beere fun igba miliọnu Naira lọwọ ile iwosan UCH, fun bi ile iwosan naa ṣe ja igbẹkẹle awọn kulẹ pẹlu bo ṣe jẹki aworan iku rẹ lu sita.

Alukoro ile iwosan naa, ọgbẹni Toye Akinrinlọla, lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lo fi idi ọrọ yi mulẹ

''A ti gba iwe ti awọn ẹbi Olatoye kọ si wa lori iku ọmọ wọn sugbọn awọn agbẹjọro wa yoo fesi si pada fun wọn bo ti ṣe tọ ati bi o ti ṣe yẹ''

Akinrinọla ni oun ko le fesi si awọn ọrọ ti molẹbi oloogbe kọ, bi kii ṣe pe ki awọn agbẹjọro UCH wo awọn ẹsun naa wo yekeyeke, ki wọn si dahun si.

Àkọlé fídíò, Ẹgbọ́n olóògbé Suga: Wọ́n yìnbọn fún Suga lójú mi, n kò sì lè dá wọn dúró

Ile iwosan nla UCH ni ilu Ibadan ni Olatoye ku si, ni ọjọ Kẹsan oṣu Kẹta ọdun 2019, lẹyin ti o fara gba ọta ibọn ni agbegbe Lalupọn lasiko idibo sipo gomina to waye nibẹ.

Agbẹjọro mọlẹbi Sugar, Amofin C.C Amedu ti ile iṣẹ agbẹjọro Ikeh Sunday, Ibadan, ninu iwe ipẹjọ fẹsun kan ile iwosan UCH pe, wọn jẹ ki aworan ipọkaka iku Sugar lu sita lasiko to wa gba itọju lọdọ wọn.

Àkọlé fídíò, Manfe-Dove: Àgbà ìlú kan ní ohùn kan ló fọ̀ sáwọn baba ńlá àwọn láti ṣe bẹ́ẹ̀

Wọn fi iwe ipẹjọ naa ṣọwọ si minisita fun eto ilera ati ẹgbẹ awọn dokita ẹka tilu Ibadan.

Iwe naa sọ siwaju pe, ti UCH ko ba fesi si ọrọ awọn laarin ọjọ meje, awọn yoo gbe igbesẹ lati pe wọn lẹjọ lori ẹsun aibikita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Akẹ́kọ̀ọ́ dókítà: Fásitì Ìbàdàn gbọdọ̀ dín owó iléẹ̀kọ́ wa