Delta: Ọ̀fẹ́ nilé ìwé, kò yẹ kí wọn lé akẹ́kọ̀ọ́ torí owó

Oríṣun àwòrán, @aduakedet
Kangun kangun kangun, o ti wa kangun sibi kan fun ọga ile iwe kan to le akẹkọ rẹ lọ sile nipinlẹ Delta.
Akẹkọ naa, Success Adebor, to n lọ sile iwe alakọbẹrẹ Okotie-Ebor kinni nijọba ibilẹ Sapele, ni fidio rẹ lu awọn oju opo itakun agbaye pa, lasiko to n fapa janu pe, wọn le oun kuro nile ẹkọ tori pe oun ko ri owo ile iwe san.
Success ninu fidio naa ni, o ba oun lara mu ki wọn fi ẹgba na oun tori oun ko ri owo ile iwe san, dipo ki wọn le oun lọ sile.
Success ni wọn yoo na oun titi, nigba to ba rẹ ẹgba, ni wn yoo dawọ duro.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa ‘Ajala Travels’?
- Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde
- 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
- Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
Fidio naa ti wa pe akiyesi ijọba ipinlẹ Delta si awọn isẹlẹ to n waye nile ẹkọ rẹ.
Lọwọlọwọ bayii, ijọba ti pasẹ fun ọga ileẹkọ alakọbẹrẹ naa, arabinrin Vero Igbigwe lati lọ rọọkun nile na, nitori bo se le akẹkọbinrin naa nile iwe rẹ.
Kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Delta, Amofin Chiedu Ebie, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni, ọga ile iwe naa ko lee se alaye ohun ti owo to n beere lọwọ Success wa fun, tori ọfẹ ni ẹkọ alakọbẹrẹ nipinlẹ naa.
Wayi o, ọ̀pọ awọn lookọ lookọ lawujọ lo ti n rọ ojo owo ati dukia fun success, to ti kekere jẹnu ṣamuṣamu ninu fidio ọhun, to si ti pada sile iwe.













