Boko Haram: Bó ṣe ń yìnbọn, ló tún kó ìlú náà lẹ́rú

Awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Akọtun jinnijinni lo tun ba ilu Michika, nipinlẹ Adamawa lọjọ Aje, ti ariwo ẹkun si sọ, bẹẹ ni omije n san loju awọn ara ilu naa, nigba tawọn atilaawi Boko Haram tun ba wọn lalejo.

Se ni iro ibọn n dun takotako, tawọn araalu si n sa asala fun ẹmi wọn lọ sa pamọ sabẹ oke to wa nilu naa, koda, awọn ikọ elesu ọhun tun duro ra epo sinu awọn ọkọ wọn nibi ti aaye gba wọn de.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ilu Michika lo raye ra pala lọ fara soko lori oke, sugbọn aanu awn eeyan to ku ninu ile yoo se eeyan pẹlu bi iro ibọn se n dara leti wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti wn n salaye ohun to sẹlẹ, ọp awn araalu naa to pe lori aago lo ni, Ikọ mujẹmujẹ Boko Haram tun ti gba ilu Michika lẹẹkeji, ti ẹmi awọn ara ilu naa si wa ninu ewu nla.

Asaaju kan lagbegbe naa, Muhammed Sanusi, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni ọwọ ẹyin lawọn agbebọn naa ba wọle, ti wn si n yinbọn laibikita, bẹẹ naa si lawn ọmọogun ko dẹkun ọna ti wọn yoo gba wagbo dẹkun fun wọn.

Àkọlé fídíò, Kloe: Èmi kìí mu òògùn olóró, àmọ́ mo fẹ́ràn láti máa wà lẹ́bà omi

O si yẹ ki atundi eto idibo waye nilu Michika yii lọjọ Satide, tawọn oloselu lọtun losi, si ti n bẹbẹ fun ibo awọn eeyan ilu naa.