Ẹbi yóò sèwádìí ohun tò pa Michael Adéyẹmọ

Oríṣun àwòrán, @Micadeyemo
Àyẹ̀wò yóò wáyé lórí òkú Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, aṣofin Michael Adeyẹmọ tó dagbere fáyé lówúrọ̀ ọjọ́ ẹtì.
Iléèwòsàn ńlá UCH nílù Ìbàdàn ni àyẹ̀wò yii yoo ti waye.Ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé náà kan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ rẹ̀ ló fi ọ̀rọ̀ yìí tó aṣojúkọ̀ròyìn BBC Yorùbá, Rótìmí Ọ̀kédáre létí nílùú Ìbàdàn.

Ó ní wọn pinnu ìgbésẹ̀ yìí láti mọ ohun gan an tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Aṣofin Michael Adeyẹmọ kú sí ilé ìwòsàn Jericho nílùú Ìbàdàn tí ìròyìn sì sọ pé àìsàn ọkàn ló paá.

Páropáro ni ile olóògbé náà dá nígbàtí akọ̀ròyìn BBC Yorùbá de ilé rẹ̀ tó wà lágbègbè Agodi GRA nílùú Ìbàdàn.
Bákanáà ní wọ́n ti ṣí ìwé ìbánikẹ́dùn kan síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórúkọ rẹ̀ .

Oríṣun àwòrán, facebook/Rt Hon Michael Adeyemo
Kí ó tó kú, ẹkùn ìdìbò ìlà oòrùn Ìbàràpá ni aṣòfin Adeyẹmọ ṣojú fún.Ṣáájú iyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, òhun ni igbákejì akójánu ilé náà.








