Queens College Lagos: Òótọ́ ni pé àìsàn bẹ́ sílẹ̀ ní Queens College - Àwọn òbí

Awọn akẹkọ Queens College
Àkọlé àwòrán, Awọn obi to ba BBC sọrọ ni lootọ ni aisan bẹ silẹ ni Queens College

Lara awọn obi to ni ọmọ ni ile iwe Queens College to wa nilu Eko ti sọ fun BBC pe, lootọ ni aisan kan bẹ silẹ nileewe naa, to si kan awọn ọmọ wọn.

Obi kan sọ fun BBC pe, ọmọ oun wa lara awọn ọmọ to fara kaasa aisan naa, bo tilẹ jẹ pe o ti gbadun bayi.

O ni "Wọn pe mi lori ẹrọ ilewọ lati wa gbe ọmọ mi, nigba ti mo de ibẹ, mo ri ọpọlọpọ awọn ọmọ ti wọn fun laye lati lọ sile latari aisan ọhun."

Damian tẹ siwaju pe, ọmọ oun n fẹ lati pada sile iwe bayi, sugbọn wọn fẹ ki ara rẹ bale diẹ sii.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn obi kan ni ahesọ lasan ni ọrọ naa, sugbọn awọn obi ti BBC ba sọrọ fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni aisan bẹ silẹ nile iwe naa.

Arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ekanem to jẹ ọkan lara awọn obi ọhun ni, ọmọ oun to wa ni ileewe naa sọ pe ọpọlọpọ lara awọn ọmọ ileewe ọhun n ṣaisan, sugbọn ṣaka lara ọmọ oun le.

Ọkọ a\won eleto ilera ipinlẹ Eko
Àkọlé àwòrán, Awọn eleto ilera ipoinlẹ Eko ti ṣabẹwo sileewe ọhun

Ijọba ipinlẹ Eko ni oun ti bẹrẹ iwaadi lọwọ lati mọ okodoro ohun to ṣẹlẹ nile iwe yiii, ati pe oun yoo bẹ awọn ile iwe miran wo fun ayẹwo.

Ikọ BBC to ṣabẹwo sile iwe Queens College foju ganni awọn eleto ilera to yọju sile iwe naa latari iṣẹlẹ ọhun.

Awọn alakoso Queens College kọ lati ba BBC sọrọ, bẹẹ ni wọn ko gba akọroyin wa lati wọ inu ọgba ile iwe ọhun.

Lara awọn akẹkọ Queens College to fọrọjomitoro ọrọ pẹlu BBC ni, ile iwe ati yara igbọnsẹ wọn nilo atunṣe ni kiakia.

Queens College Lagos: Ọmọ 85 dùbúlẹ̀ àìsàn lẹ́ẹ̀kán nàa ní Ilé ìwé Queens College!

Queens College Lagos

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ilé ìwé náà tẹ́lẹ̀rí ní àìsàn tó ń se àwọn ọmọ ile iwe naa ko nii se pelu omi mimu abi lilo.

Ile iwe Queens College ni ipinlẹ Eko ti gbe ọmọ marundinlaadọrun lọ si ile iwosan lati igba ti wọn ti wọ ile iwe ti saa yii lọsu kẹsan an ọdun.

Agbẹnusọ ẹgbẹ awọn obi ati awọn olukọ ile iwe Queens College, Ify Nwoye ni lati bii ọsẹ kan ni oun ti n gbọ iroyin pe wọn n gbe awọn ọmọ digbadigba lọ si ile iwosan.

Amọ, Akowe ile iwe naa, Ayomide Onakoya ni lati igba ti isẹlẹ naa ti bẹrẹ ni awọn ti bẹrẹ si ni se iwadii.

Onakoya ni iwadii igbimọ awọn eleto ilera naa fihan wi pe aisan naa ko nii se pẹlu omi ti wọn mu gẹgẹ bi awọn kan ṣe sọ, nitori ọna ọfun wọn ni aisan naa ti n ba wọn ja, kii se ni inu.

Àkọlé fídíò, Intersextuality: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo

Ile iwe naa fikun un wi pe lara awọn ami ti awọn ọmọ naa n fihan ni ikọ ati Catarrh pẹlu ẹfọri ati ara gbigbona.

Opọlọpọ iwadii ti awọn igbimọ eto ilera ile iwe Queens College ti ṣe ni wọn gba pe o yẹ ki o fi ọkan obi ati alagbatọ balẹ pe kii ṣe ajẹkalẹ arun lo n ṣẹlẹ lọwọ ni ile iwe naa.

Àkọlé fídíò, Blacksmith: èmí ni ìran keje tó jogún iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ yii- Alatiṣe

Bakan naa ni wọn fikun un wi pe, ile-isẹ eto iwosan, ẹgbẹ awọn obi ati ẹgbe awọn ọmọ ile iwe naa tẹlẹri n sisẹ papọ lati ri i wi pe opin ba aisan ni ni ile-iwe Queens College!

Àkọlé fídíò, Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....