Blacksmith: èmí ni ìran keje tó jogún iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ yii- Alatiṣe

Àkọlé fídíò, Blacksmith: èmí ni ìran keje tó jogún iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ yii- Alatiṣe

Iṣẹ Ajogunba lati iran keje ti baba nla mi, Ogundipe Alatiṣe ni mo yan laayo- Isiaka

BBC kọ lati jẹ ki iṣẹ ajogunba Yoruba ko parun la ṣe jade tun lọ kọ nipa iṣẹ agbẹdẹ ni ṣiṣe.

Iṣẹ agbẹdẹ jẹ ọkan lara iṣẹ ajogunba iran Yoruba ti awọn baba nla wa n ṣe yatọ si awọn miran bii: oloola, irun didi, agbẹ, ọdẹ, agbẹgilere ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọdọ Isiaka Alatiṣe, afinju alagbẹdẹ to n rọ bàbá, òjé, idẹ àti irin ni BBC gba lọ ni ilu Abẹokuta to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun ni Guusu Naijiria.

Oriṣi iṣẹ agbẹdẹ marun un ni Isiaka Alatiṣe, ogbontarigi alagbẹdẹ labẹ Olumọ mẹnuba ninu ifọrọwanilẹnuwo yii.

Akọkọ ni Agbẹdẹ oni panpẹ ti wọn n rọ panpẹ, ọkọ ada atawọn ohun eelo miran.

Ikeji ni Agbẹdẹ oni wura ti wọn n fi goolu da ara to wu wọn bii rirọ ẹgba ọwọ, ẹgba ẹsẹ ati ẹgba ọrun.

Ẹlẹẹkẹta ni Agbẹdẹ Alabẹ ti wọn n rọ ohun eelo awọn Alabẹde ati ololoola.

Ikẹrin ni Agbẹdẹ Oni idẹ, òjé, bàbà bii ti Alatiṣe Isiaka tó n yá èré, ade idẹ Oba, agada ọpa àṣẹ Ijoye ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ikarun un lawọn agba Agbẹdẹ ti wọn n ṣiṣẹ Ogun loju mejeeji ti wọn n fi irin rọ ibọn atawọn ohun ija ogun.

Isiaka Alatiṣe ṣalaye bi iṣẹ yii ṣe jẹ ti iran keje ninu ẹbi rẹ to bẹrẹ lati ọwọ Ogundipe Alatiṣe, baba nla rẹ.

Bakan naa ni Isiaka sọ nipa bo ṣe n kọ awọn èwe inu agboole rẹ ki o le fi le wọn lọwọ lọjọ ọla ati awọn ipenija inu iṣẹ agbẹdẹ ni Naijiria lasiko yii.