#BBCGovDebate: Olùdíje 5 ni yóò kópa nínú ìpàdé ìtagbangba l‘Ogun
Gẹgẹ bi ise rẹ, BBC News Yoruba tun ti gbe ipade ita gbangba to n se fawọn oludije fun ipo gomina de ipinlẹ Ogun.
Gbọngan nla Olusẹgun Ọbasanjọ to wa nilu Abẹokuta ni ipade ita gbangba naa yoo ti waye ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹjọ osu Keji ọdun 2019.
Aago mẹsan aarọ ni ijiroro naa yoo gbera sọ pẹlu oludije fun ipo gomina marun ti a ti fiwe pe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀rọ̀ LAUTECH gba àpérò f'áwọn Olúdíje Ọṣun
- Báwo ni àwọn olùdíje Oyo ṣe fẹ́ kojú ìṣòro ìlera?
- Ìpínlẹ̀ Oyo gbàlejò ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
- Makinde, Sharafadeen yọ ra wọn níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC l'Ọyọ
- "Bí mo bá dé ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara..."
- Ta ni yoo ra ọkàn aráàlú ní Kwara lónìí?
- #BBCOyoDebate: Àwọn olùdìbò ìpínlẹ̀ Ọyọ fohùn sílẹ̀ lórí àwọn oludije ti kò yọju
Lara awọn ẹgbẹ oselu ti oludije wọn yoo maa kopa ninu ijororo naa ni ẹgbẹ oselu APM, ADC, APC, ANN ati LP.
Gbogbo awọn eeyan ipinlẹ ogun ni a n rọ lati lọ fi orukọ silẹ lori Facebook BBC News Yoruba ko to di ọjọ naa.