BBC Gov Debates: Ètò ìlera alábọ́dé la ó ṣe fún àwọn ènìyàn Ọyọ
Gbogbo oludije ni wọn bere bi wọn yoo ṣe koju iṣoro abo nipinlẹ Ọyọ.
Adedibu ni ilera alabọ̀de ni oun yoo kọkọ dojú kọ tori pe Yoruba ni ati kekere la ti n pẹka iroko. Nitorinaa, ilera to le ṣeranwọ kanmọ kanmọ̀ oun yoo kọkọ doju kọ.
Sẹnetọ Lanlẹhin naa ni ilera alabde yoo wulo ni awọn wọọdu kọọkan wọn si ni gbogbo nkan irinṣẹ to yẹ pẹ̀lu amojuto to bẹẹ́ ti wọn ko ni nilo lati maa lọ si ile iwosan ti ijọba ni gbogbo igba.
Arabinrin Bolanle Sarumi- Aliyu ni eto ilera ọfẹ loun yoo fun awọn ara ipinlẹ Ọyọ nitori oun rii pe ọpọ iyalọmọ gan lo n jiya to si n ko ba ọmọ̀. Bakan naa, ko yọ itọju arugbo silẹ.
Ni ti oloye Alao Akala, o ni ohun ti ni iriri nipa ṣiṣe ibẹwo si awọn ibudo iwosan to wa ni awọn wọọdu ipinl Ọyọ kaakiri oun yoo si ṣamojuto wọn sii nitoripe oun naa loun gbe wọn sibẹ nigba iṣejọba oun akọkọ gẹgẹ bii gomina Ọyọ. Oun naa ṣeleri lati mojuto awọn arugbo pẹlu ilera ọfẹ.