Ẹ ká bí ìjíròrò láàrin àwọn olùdíje gómìnà Ọyọ ṣe lọ
A ko ni rii ju bayii lọ. Ẹ ka bi ijiroro laarin awọn oludije sipo gomina Ọyọ ṣe lọ.
Ìròyìn àti àlàyé lórí ìjíròrò láàrin àwọn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ láti gbàngàn UCH ní Ibadan
Abdulwasiu Hassan
A ko ni rii ju bayii lọ. Ẹ ka bi ijiroro laarin awọn oludije sipo gomina Ọyọ ṣe lọ.
Sarumi nio ni ojn yoo rii daju pe gbogbo omo to n gbe nipinle Oyo ni won n gbe.igbe aye to ni iyi ati ogo. O ni ko ni si oun to n jẹ gbọmulelanta mọ nitori oun yoo seto owooya fawon araalu.
O ro awon ọdọ lati maṣe faye gba awon oloṣelu ku won lo wọn fun iwa jagidijagan.

Senato Lanlehin ki awon ara ipinle Oyo. O ni oun ti se ijoba rii ti oun se iwonba ti oun lee se. O niijoba tiwantiwa loun fẹ mu wa. Oun ko wa owo lọ sinu iṣejọba. O ni okun wa, agbara wa, ọpọlọ si tun wa

Akala dupẹ fun awon eeyan ti won jade wa. Ijoba tiwantiwa, ijoba araalu, ti yoo pa araalu lẹrin ni oun yoo ṣe.

Lori ijọba ibilẹ, gbogbo awọn oludije ni wọn ni awọn yoo da idaduro ijọba ibilẹ pada

Akala sọ pé oun ko nii maa gbe iṣe ti awọn ara Ọyọ le ṣe fun awọn ara ita.

Lórí ìbérè pé Adelabu ń lo jàndùkú fún ìpòlóngo, Adelabu ni rara o . Ọrọ naa ko ri bẹẹ.

Adebayo Adelabu sọ pe oun yoo gbe iṣe agbe larugẹ. O ni oun yoo koju si Oke Ogun fun nnkan ọgbin jijẹ ati tita.

Sarumi ni awọn akanda ẹda ti n dojukọ idẹyẹsi l'awọn bank ati bẹẹbẹ. O ni oun yoo fopin si idẹyẹsi. Ati pe awon ileewe ti gbogbo ọmọ ba n lọ ni awọn akanda naa yoo maa lo

Lanlehin ni oun yoo se atunsẹ ileewe awọn akanda ẹda.o ni oun yoo ya owo soọtọ fun eto ẹkọ ọfẹ fawon akanda

Adelabu ni oun yoo satunse awon ibudo ati ileewe akanda ẹda kaakiri ipinlẹ Oyo. O ni oun yoo tun yan awon akanda si ipo iṣejọba

Akala ni lasiko ti oun se gomina lakọkọ, oun yan akanda eda kan si ipo amugbalegbe oun. Ati pe oun yoo tu ileewe awọn akanda ẹda ṣe

Gbogbo awọn oludije lo ni awọn yoo san owo osu to kere ju fun awon oṣiṣẹ N30,000.
Fọfọ ni Gbongan kun fun eto ilade itagbangba fawon olidije ni ipinle Oyo.


Oríṣun àwòrán, .
Adelabu ni wọn o jẹ oun lowo oṣu rii nitori naa ko si idi fun oun lati jẹ owo osu. O ni oun yoo lo iriri gẹgẹ bi olusiro owo lati rii pe owo to n wọlẹ sapo ijoba
Sarumi ni ina apa lo n damu aṣueọn ipinlẹ Ọyọ. O ni ko ni si ofiisi ọkọ gomina nitori ọkọ oun ko faramọ oṣelu ṣiṣe

Akala ni ko le si isoro lori owo osu. O ni bi oun ba de ipo oun yoo san owo osu to kere ju minimum wage N30,000.

Lanlehin dahuun pe owo nina yoo wa fun awon ohun to tọ. Ohun ko ni bẹrẹ iṣẹ ti oun ko ni lee pari. O ni awọn oṣiṣẹ ijọba ni yoo maa gba isẹ naa dipo awọn kongila.

Lori BBC, akala ni oun ti se ipa nla lori ọrọ BCOS gẹgẹ bí oun ti se tele. Lanlehin ni oun yoo rii pe ifidimulo idanileko wa. Sarumi ni oun yoo ṣiṣẹ pẹlu BBC lati gbee soke. Adelabu ni oun yoo da ogo BCOS pada.

Sarumi ni oun yoo gba lautech pada fun ipinlẹ Oyo. O ni oun yoo si tun kọ fasiti tuntun. O ni wahala to n de ba eto ẹkọ naa ni gbigba awọn olukọ oloṣelu nitori awon oloselu lo gba wọn lai je pe won kun oju iwọn

Lanlehin ni oun yoo wa iyanju ṣi ọrọ eni to ni fasiti Lautech. O ni ijiroro yoo waye.ki oyo lee jogun Lautech. Wọn yoo si san ẹtọ to ba yẹ fun ipinlẹ Osun. O ni eto ẹkọ ọfẹ yoo wa fawon ileewe alakobere ati girama
