BBC Gov Debate: Àwọn olùdíje gómìnà Oyo gbà lati san 30,000N owó osù òsìsẹ́

Àwọn olùdíje gómìnà Oyo
Àkọlé àwòrán, Àwọn olùdíje gómìnà Oyo

Awon oludije mẹrin lo kopa nibi ipade itagbangba BBC News Yoruba to waye nilu Ibadan. Awọn to wa nibẹ ni, Adebayo Alao Akala ADP, Adebayo Adelabu APC, Olufemi Lanlẹhin ADC ati Bolanle Sarumi Aliyu NIP.

Lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ ti wọn beere lọwọ awọn oludije, gbogbo wọn pa ẹnu pọ lati sọ pe awọn yoo san N30,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣisẹ to kere ju. Bakan naa, wọn mnu ba ọna ti wọn yoo gba lati ri owo ọhun san.

Ẹwẹ, nigba ti Ọtunba Alao Akala da nikan sọ pe ohun iwuri ni oṣelu Naijiria latyin wa, idakeji ni awọn oludije mẹta to ku fnu ko le lori pe oṣelu Naijiria ko ṣee mu yangan.

Lara awọn koko ọrọ mii ti wọn mẹnu ba lọlọkan ojọkan niyii.

Bolanle Sarumi-Aliyu - NIP

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Bolanle Sarumi ni gbogbo awon ọmọ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju marun lọ yoo gba eto ilera ofe. Bakan naa ni awon arugbo ti ọjọ ori wọn ko din ni odun marundinlaadota yoo maa janfani eto ilera ọfẹ bi oun ba wọlé.

O ni iru awọn ọna ti ko tọ ti awọn kan n lo lati kowo jẹ ko ni ṣi silẹ ni ijọba oun. Fun apẹrẹ, "ko ni si ọfiisi ọkọ gomina ninu iṣejọba temi".

Lori ọrọ abo, Sarumi ni aisi olori gidi ni kii mu ki ilu toro. O ni ko lee si abo laisi iṣẹ. O ni oun yoo ro awọn ọdọ lagbara.

Ọtunba Alao Akala - ADP

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Pẹlu iwadii ati ibẹwo ti Akala ni awọn ṣe kaakiri wọn rii pe eto ilera ko koju osuwọn to. O sọrọ lori aṣeyọri iṣejọba rẹ akọkọ nigba to jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ.

Nitorinaa, Akala ni agbalagba bii t'oun to ni ọpọlọpọ iriri ni ipo gomina Ọyọ tọ si lọdun 2019.

Alao Akala ni saa isejọba oun akọkọ ohun da awọn eto ilera alabode ẹsẹ kuku silẹ. O ni ni ile iwosan nla Adeoyo ko sí ẹrọ amunawa to dara. Ati pe ohun yoo ṣe agbekalẹ ilera ọfẹ.

Alao akala ni gẹgẹ bii Ọlọpaa to ti feyinti oun mọ ọna abayọ si ipenija ọrọ abo. Oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati mu eto abo gbopọn sii.

Adebayọ Adelabu - APC

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Lori ọrọ eto ilera, Adelabu ni ilera jẹ ara ohun mẹta ti iṣejọba oun la kalẹ. Awọn to ku ni iṣẹ agbe, eto ẹkọ ati ilera.

Eto ilera alabọde ni Adelabu ni awọn yoo kọ si awọn igberiko. Aisan to le koko ni wọn n gbe lọ ile iwosan ijọba tabi ti akọṣẹmọṣẹ.

Ni ti abo, o ni ohun ti ko ni jẹ ki nkan buruku sẹlẹ ni ijọba oun yoo gbajumọ. O fi kun un pe awọn yoo rii pe awọn ọdọ n kọ iṣẹ ọwọ wọn si n kopa ninu ere idaraya bọọlu

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin ọmọ Yorùba, kí ló le nínú fí fí àmì sí A-la-pa-n-dẹ-dẹ?

Olufẹmi Lanlẹhin - ADC

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àwọn olùdíje gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àwọn olùdíje gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ

Lanlẹhin ni tirẹ salaye pe nitori bi ipinlẹ Ọyọ ṣe tobi kun ara ohun to n fa ipenija eto ilera. Nitori naa iṣejoba oun yoo pese ileewosan alabọde kaakiri wọọdu.

Lanlẹhin ni lori eto abo ni ohun to n fa wahala ni ilu yoo gba amojuto nipa ipese iṣẹ. "Ko si ẹni fẹ ṣe jagidijagan to ba ri iṣẹ ṣe." O ni eto idaṣẹsilẹ, eto ọgbin ati ileeṣẹ kereje fun igbaniisiṣẹ.