BBC Gov Debate: Makinde, Sharafadeen yọ ra wọn níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC l'Ọyọ

Lara gbogbo awọn oludije ti wọn kọwe pe gẹgẹ bi awọn eniyan ṣe sọ pe awọn fẹ ẹ ṣugbọn meji ninu awọn ti wọn pe kọ lati yọju sibẹ.
Olùdíje fún ipò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Zenith Labour Party, ZLP, Sharafadeen Alli kò sí níbi ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá ó si ti kọ́kọ́ jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé òun yóò wà.
Bakan naa, oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Seyi Makinde naa ko yọju sibi ipade ifọrọwerọ naa.
BBC Yoruba ti ṣaaju ṣe ohun to tọ lati ranṣẹ pe gbogbo awọn oludije ti awọn ti yoo dibo ni awọn nifẹẹ lati ri nibi ipade ifọrọwerọ naa.
Ẹwẹ,. gbogbo awọn oludije to yọju lo wu awọn eniyan lori pẹlu gbogbo alakalẹ aato wọn lọlọkan o jọkan ti wọn ni awọn yoo gbe ṣe bi awọn ba di gomina ipinlẹ Ọyọ.









