BBC Gov Debates: Lónìí ni ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Bi a da ọjọ, ọjọ a pe bi a da igba, igba a ko. Igbaradi ti bẹrẹ ni pẹrẹwu fun ipade ifọrọwerọ laarin awọn oludije gomina ni ipinlẹ Ọyọ eyi ti BBC Yoruba ṣe agbekalẹ rẹ.

Gbogbo awọn oludije ti awọn oludibo yan pe awọn fẹ ri ni BBC Yoruba ti pe wa sibi ipade itagbangba naa.

Àkọlé fídíò, Wòlìí Arole polongo ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Agogo mẹwaa owurọ gerege ni eto naa yoo bẹrẹ. Latari eyi awọn akopa ti n de sibi eto naa lati forukọ silẹ.

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Bakan naa, itage ti to fun awọn oludije, gbogbo ijoko awọn olukopa lo si ti ni ẹbun orisirisi ti BBC ko wa lati mọ riri pe wọn kopa.

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Awọn oṣiṣẹ alaabo gan ko gbẹ́yin gẹgẹ bi wọn ṣe ti wa ni ṣẹpẹ fun amojuto abo to peye layika ati ninu gbọngan eto.

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé fídíò, Ìpínlẹ̀ Oyo gbàlejò ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá