Ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá: Gbọ̀ngàn Mapo ṣeé mú yangàn ní Ibadan
Ọjọ kan ṣosọ lo ku ti ipade ita gbangba ti BBC Yoruba ṣe agbekalẹ rẹ fun awọn oludije fun ipo gomina nipinlẹ Oyo.
Ni agogo mẹsan aarọ ọjọ Ẹti ni eto naa yoo bẹrẹ ni gbangan Ọjọgbọn Theophilus Ogunlesi nidojukọ ọgba UCH.
Ṣugbọn ẹ jẹ ki a sọrọ nipa gbangan Mapo to kalẹ si ilu Ibadan nibi ti ole ti n jare olohun.

Gbọngan Mapo re e to kalẹ sori oke Mapo ti wọn fi sọ orukọ rẹ nilu Ibadan. Nibi ni awọn ọmọbibi ilu ti maa n ṣepade ọrọ oṣelu, ọrọ idagbasoke ati ilọsiwaju ilu Ibadan.

Ẹni to ba duro lori oke Mapo, kedere ni yoo maa ri gbogbo ilu Ibadan ninu ogo rẹ.

Awọn opo to di gbọngan Mapo mu lo n ṣe apejuwe oke meje to yi ilu Ibadan ka. Gbogbo oke yii ni wọn si mọ opo si.

Tabili yii ni wọn maa n tẹ awọn oku Olubadan to ba ti waja si ki gbogbo ara ilu le rii.

Gbọngan Mapo tobi gan, bẹẹ lo laye daadaa lati gba ọpọlọpọ eeyan. Nibayii gbogbo eto lo ti wa ni ṣẹpẹ bayi ṣaaju ipade itagbangba BBC Yoruba lọjọ Ẹti, ẹ jẹki a jọ pade nibẹ lọla.












