'Wọn ko ni nkan ṣe fún ipinlẹ Ọyọ ni' #BBCGovDebate

Àkọlé fídíò, 'Wọn ko ni nkan ṣe fún ipinlẹ Ọyọ ni' #BBCGovDebate

Ero awọn eniyan ipinlẹ Ọyọ ṣọtọọtọ.

Lọjọ kinni, oṣu keji, ọdun 2018 ni BBC Yoruba ṣeto ipade itagbangba Link fawọn oludije ipo gomina nipinlẹ Oyo.

BBC ṣeto yii ki awọn oludibo le mọ nipa agbara ti ìka wọn ni lati yan ẹni to ni ero rere lọkan fun wọn.Link

Ati pe ki awọn oludije le ni pepele oore ọfẹ lati sọ ohun ti wọn ni lọkan lati ṣe fawọn ara ilu.

BBC Yoruba fi ilede sita pe ki awọn eniyan ipinlẹ Oyo sọ ẹni ti wọn fẹ ri ninu awọn oludije mẹtadinlogoji ti ajọ eleto idibo INEC gbe sita lati dije dupo gomina.

BBC kan si gbogbo awọn ti awọn eniyan ni wọn fẹ ri pata bi o ti yẹ.

Awọn ti a ri lọjọ naa ti wọn ni oore ọfẹ lati sọ ona abayọ si iṣoro awọn eniyan ipinlẹ Ọyọ ni:

Otunba Alao Akala ti ẹgbẹ ADP

Oloye Adebayọ Adelabu ti ẹgbẹ APc

Senetọ Olufẹmi Lanlẹhin ti ADC ati

Omobabinrin Bolanle Sarumi-Aliyu ti ẹgbẹ NIP

Awọn oludije meji mii ti awọn oludibo yan pé awọn fẹ ri ti BBC kan si lọn ato yẹ ni Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti ẹgbẹ PDP ati Alhaji Sharafa Alli ti ẹgbẹ oṣelu ZLP.

Ṣugbọn titi ti BBC fi pari ijiroro naa ni a ko ri awọn mejeeji Makinde, Sharafadeen yọ ra wọn níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC l'Ọyọ

Ni kete ti eto yii pari ni awọn oludibo to wa ni gbọngan Ogunlesi ti eto yii ti waye fi ero wọn han fun BBC pe ẹnikẹni to ba ka oludibo to pa iṣẹ rẹ ti wa gbọ nipa ọjọ iwaju ipinlẹ Ọyọ yẹ ko wa nibẹ.

Ọpọlọpọ kaa si iwa arifin ati afojudi pé oludije kan ko yọju sawọn oludibo to maa to sinu oorun dibo fun oun.

BBC Yoruba ko ṣeto ipade itagbangba yii lati dọti ẹnikẹni tabi lati tabuku ẹnikéni rara.

Idi pataki ti a ṣe gbe ekaleẹ ni pe ki awọn eniyan tubọ ni imọ kikun lori iṣejọba Tiwantiwa ati mundun mudun to yẹ ki ara ilu ni gẹgẹ