'A ni òfin púpọ̀ ní Naijiria ṣùgbọ́n a kò bọ́wọ́ fún un ni'
Ìmúṣẹ ìlérí ló ṣe pàtàkì jùlọ lásìkò yii.
Lọjọ kinni, oṣu keji, ọdun 2018 ni BBC Yoruba ṣeto ipade itagbangba pẹlu awọn oludije dupo gomina ni ipinlẹ Ọyọ.
Eyi waye ni gbongan Ogunlesi ni UCH ni fasiti Ibadan ni eyi tawọn oludibo ti raye wa beere ohun ti wón fẹ lọwọ oludije.
Ero awọn eniyan ipinlẹ Oyọ ṣotọọtọ lẹyin ipade itagbangba yii, ọpọ ni lẹyin eto yii, awọn ti mọ ẹni ti awọn yoo dibo fun.
Awọn ti wọn kopa ninu eto naa ni Otunba Alao Akala ti ẹgbẹ oṣelu ADP; Oloye Adebayọ Adelabu ti ẹgbẹ APC; Senatọ Olufẹmi Lanlẹhin ti ẹgbẹ ADC àti Ọmọbabinrin Bọlanle Sarumi-Aliyu ti ẹgbẹ NIP.
Awọn mii ti awọn oludibo yan pé ki BBC pé ṣugbọn ti wọn ko yọju ni Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti ẹgbẹ PDP ati Alhaji Sharafa Alli ti ẹgbẹ ZLP.
Ọpọlọpọ olukopa lo gboriyin fun BBC fun ṣiṣe agbekalẹ irufẹ eto nla bayii to fun awọn loore ọfẹ lati gbọ lati ẹnu oludije kọọkan fun ra wọn.
Bakan naa ni wọn sọrọ lori ohun ti wọn gbọ nibi eto naa.
Lakotan, gbogbo wọn ni olori to bẹru Ọlọrun lawọn n fẹ ti yoo mu ileri rẹ ṣẹ.
- Ààrẹ Gani Adams sọ ẹni tí Yorùbá yóò dìbò fún ní ọdun 2019 #BBCNigeria2019
- Day 18: Ṣé o fẹ́ mọ òtítọ́ nínu ọ̀rọ̀ ìpolongo àwọn oludije sípò aarẹ Naijiria? #BBCElection2019.
- Day18: Àwọn oludije Naijiria ṣetán láti gba ẹ̀jẹ̀ nidibo 2019 - Falana #BBCElection2019
- Link
- Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Eko