Ayẹwo<br>lati mọ otitọ.
Ootọ diẹ wa lara ọrọ yii. Buhari sọ otitiọ nipa pe orilẹede Naijiria lawọn eeyan to n ṣe igbọnsẹ si ita gbangba pọ si julọ ṣekeji lagbaye, eyi to tums si pe wọn ko lanfani si ile igbọnsẹ to dara. Orilẹede India nikan eyi ti pọ ju ti Naijiria lọ.
O le ni miliọnu mẹrindinlaadọta ọmọ Naijiria to n ṣe igbọnsẹ si ita gbangba gẹgẹ bi ilana atọka idagbasoke ti banki agbaye gbe kalẹ ṣe sọ. Eyi n lọ si bii ida kan ninu mẹrin gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria.
Amọ iyatọ wa lori iye yii lẹlẹkunjẹkun. Ipinlẹ mẹta ti ọwọja igbọnsẹ itagbangba wa ni Kogi, Plateau ati Benue nibi ti o le ni idaji awọn eeyan ibẹ ko ti lanfani si ile igbọnsẹ lilo, iyẹn gẹgẹbi iwadii ajọ ilera agbaye ati ajọ idagbasoke eto ẹkọ awọn ewe lagbaye, UNICEF gbe kalẹ lọdun 2016/2017.
O din ni ida marun awọn eeyan ipinlẹ bii Borno, Zamfara, Kano, Abia ati ipinlẹ Eko ti wọn n ṣe igbọnsẹ si itagbangba.
Loni ilọpo meji ọwọja ṣiṣe igbọnsẹ sitagbangba lawọn ilu nlanla lo n waye lawọn igberiko bayii, amọṣa ọwọja rẹ a maa pọ lawọn ilu ti eeyan pọ si, eleyi ton kọni lominu nipa awọn ipinlẹ bii Eko.
Oniruru aisan ninu eyi ti aisan gbẹmi-gbẹmi igbẹ gbuuru wa ti o si lee waye nitori awọn ounjẹ ati omi ti ko mọ ati ayika ti ko ni imọtoto, eto kolẹ-kodọti ti ko duro deede atawọn iwa ilera to mẹhẹ bii aikii fi ọṣẹ ati omi fọwọ.
Buhari woye adinku to niye ninu iye awọn to n lanfani si eto igbọnṣẹ to kunna to da lori oniruuru ile igbọnsẹ, omi to jagaara fun didana ati mimu.
Abajade iwadii ajọṣe kan laarin ajọ ilera agbaye, WHO ati ajọ idagbasoke eto ẹkọ awọn ewe lagbaye, UNICEF (JMP) gbe kalẹ lọdun 2015 fi idi eleyi mulẹ, ṣugbọn eyi yatọ si ohun ti Buhari n sọ.
Ni ọdun 1990, ajọ WHO woye pe ida mejidinlogoji ninu ọgọrun awọn eeyan lo lanfani si ohun elo imọtoto, eyi si ti di ida marundinlọgbọn lọdun 2015.
Wahala ọpọ ọdun pẹlu ti ni ipa pupọ lori awọn ohun elo amayedẹrun to lee faye gba ipese omi to ja gaara ati ile igbọnsẹ, paapaa julọ lawọn agbegbe ni ẹkun ila oorun ariwa.
Loni ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọpọ awọn ipinlẹ lo lanfani si omi to mọ gaara, ṣugbọn kii ṣe omi ẹrọ ijọba.
Ni gbogbo Naijiria, olu ilu Naijiria, Abuja nikan lawọn eeyan to n janfani omi ẹrọ ijọba ninu ile wọn ti pọ ju eeyan kan ninu mẹwa lọ.
Kọngadẹrọ ni ida kan ninu mẹta awọn ọmọ Naijiria ti n ri anfani omi to mọ fun mimu.
Ni apa ariwa, meji ninu marun ile to wa nibẹ ni ko ni anfani omi to mọ.