Àgbálùmọ̀, ohun mẹ́fà tó ń ṣe lára tí o kò mọ̀

Àgbálùmọ̀
Àkọlé àwòrán, Àgbálùmọ̀
Àkọlé fídíò, Àgbálùmọ̀ àti ìwúlò rẹ̀

Bii ti awọn eso miiran ti ẹ mọ, agbalumọ ni ọpọlọpọ nkan to fi n se ara loore.

Gẹgẹ bi asiko ti eso yii maa n jade ti de bayii, ọpọlọpọ fẹran lati maa gbadun aadun tabi kikan rẹ.

Ṣugbọn pupọ ninu wọn ni ko fi bẹẹ mọ awọn ore to n se fun agọ ara. Awọn oni sayẹnsi n pe e ni Chrysophyllum Albidum.

Àgbálùmọ̀
Àkọlé àwòrán, Àgbálùmọ̀

Lawọn igberiko ni wọn ti maa n saba gbin agbalumọ laarin oṣu kejila ọdun si inu oṣu kẹrin ọdun tuntun lo maa n jade.

Yala o ti pọn loju tabi ko tii pọn, ọpọlọpọ kii le mọ boya eyi to ti jade ṣi kan tabi o ti ni adidun. Ṣugbọn awọn mii a maa fi iye igba ti ojo ti rọ sii lori igi mọ boya o ti ni adidun.

Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

Iwadii fi han pe agbalumọ kan ṣoṣo ni to ohun amuṣagbara mẹtadinlaadọrin to n ṣe ara loore.

Ẹ wo isọri awọn pataki iṣẹ ti eso kekere yii n ṣe.

Àgbálùmọ̀
Àkọlé àwòrán, Àgbálùmọ̀
  • Iwadii fi han pe agbalumọ kan ṣoṣo ni to ohun amuṣagbara mẹtadinlaadọrin to n ṣe ara loore.
  • Oogun ti wọn ṣe latara eso Vitamin C pọ lara rẹ eyi to maa n wọya ija pẹlu awn aisan ọta ara, aisan ọkan, aisan to n ṣaju ibimọ, arun oju koda ati ara hihun jọ. Lara irufẹ ohun ti a n jẹ si lati le ri Vitamin C.
Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ
  • O jẹ ẹrọ funra rẹ ti ọlọrun da. Omi adidun to maa n jade latara agbalumọ wulo fun bii eyin didun, inu kikun, ọna ọfun ati erigi didun ati bẹẹ lọ. Ko da itan s pe wọn maa n fi koro inu rẹ tọju aisan oju ara obinrin tabi kokoro ara lawọn ilu kọọkan.
  • O tun jẹ ẹrọ fun awn aisan to le sare pa agọ ara. O maa n da abo bo ẹran ara lodi si awọn aisan asare ja.
  • O wulo fun ẹni to ba fẹ jo. Fun anfani awọn to sanra tabi ti ko fẹ sanra pupọ. Bi o ṣe kere to lo ṣe n ṣe iṣẹ nla fun ẹni ti ko ba fẹ bu sara.
  • Agbalumọ dara fun oloyun.
Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife