FRSC Covid 19 laws: Awakọ̀ ojú pópó san N26,000 nítorí ó lu òfin tó de ìtànkálẹ̀ ààrùn Covid-19

FRSC

Oríṣun àwòrán, Google

Ajọ to n risi ọrọ oju popo, FRSC ti fi ikilọ lede pe awọn eniyan to n jade lai lọ ibomu kaakiri yoo fi oju wina ofin.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹka ileeṣẹ FRSC ni ipinlẹ Bauchi ṣe fi panpẹ ọba mu awakọ to rufin aarun Covid-19.

Adari Ajọ FRSC nipinlẹ naa, Yusuf Abdullahi ni owo itanran ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgbọn ni o san lẹyin ti awọn eniyan to gbe si inu ọkọ ko tẹlẹ ofin titakete si ara ẹni ninu ọkọ ati awọn ẹsun miran.

O fikun pe awọn ẹṣẹ miran ti awakọ naa tun ṣẹ ni pe ko ni iwe irinna, ti ọkọ rẹ naa ko tun ni awọn iwe to peye.

Adari Ajọ FRSC ni ipinlẹ Bauchi ni ijiya naa yoo jẹ ki awọn eniyan mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe, ati eleyii ti ko ba ofin mu.

FRSC

Oríṣun àwòrán, Google

''Awakọ oju popo pẹ̀lú nọmba idanimọ ọkọ lati Eko san iye owo 26,000 nitori ko bọ̀wọ fun ofin to de Covid-19 lasiko to n gbe awọn eniyan to wa ninu ọkọ rẹ.''

''Lasiko yii ti aarun Covid-19 n ja ranyin nilẹ, a gbọdọ ri wi pe awọn awakọ ni papakọ gbọdọ tẹle ofin to de itankalẹ aarun Coronavirus ni Naijiria''

''Lara rẹ ni lilo ibomu ati fifọ ọwọ loore-koore, to fi mọ yiyago fun ara ẹni lawujọ.''

Adari ikọ FRSC naa wa lọ awọn awakọ ati awọn arinrinajo lati bọwọ fun ofin to de itankalẹ arun Covid-19 nitori fun anfaani gbogbo eniyan naa ni.

O ni awakọ to ba tẹlẹ ofin yii ko ni ri idaamu loju popo, ati pe ọkọ wọn gbọdọ wa ni ibamu lati rin ni oju popo.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo