Ondo Doctors strike: Àwọn aláìsàn ń padà lọ sílé lẹ́yìn tí àwọn Dókítà bẹ̀rẹ̀ ìyànṣẹ́lódì ní Ondo

BBC Yoruba ṣabẹwo sawọn ile iwosan ijọba ni ipinlẹ Ondo lati mọ bi nkan ṣe ri lẹyin ti awọn oniṣegun oyinbo bẹrẹ iyanṣelodi.
Nigba ti a de UNIMED Teaching hospital i Akure complex, a rii pe awọn alaisan ti n kuro nibẹ lọkọọkan lati wa ọna miran lati wa ojutu si iṣoro wọn.
Wọn ni ko si dokita kankan to yọju si wọn lati ṣe itọju wọn tabi ki wọn fun kọ ayẹwo tabi oogun fun awọn alaisan rara.
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ ìforúkọsílẹ káàdi ìbánisọ̀rọ̀ síwájú síi
- Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ mú àgùnbánirọ̀ di èrò iléẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kogi
- Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
- 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìnì fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'
Ni ile iwosan UNIMED yii kan naa ni akọroyin BBC to ṣabẹwo sibẹ ti ri awọn Nọọsi ati awọn mii ti wọn n da alaisan lohun niwọnba ti agbara wọn ba ka.
Ni wọọdi iṣẹlẹ ojiji ti wọn pe ni "emergency ward" ni akọroyin BBC de ni awọn Nọọsi ni awọn ti kọwe lọ sile iwosan mii fawọn alaisan ki wọn le lọ gba itọju nile iwosan aladani.
Arabinrin Adekunmbi Osakuade, to jẹ adele oludari ẹka naa ṣalaye fun BBC pe iyanṣẹlodi naa ti n so eso ti awọn fi ni ki awọn alaisan maa lọ sile wọn nitori ko si nkan miran ti awọn le ṣe sii.

Kini awọn alaisan ti BBC ba sọrọ sọ?
Olukọni, Christianah Borokini ṣalaye pe oun nilati wa sile iwosan naa wa gbe baba oun ti ara rẹ ko ya pada ni.
O ni ara baba oun ti n ya diẹ tẹlẹ ki iyanṣẹlodi yii to bẹrẹ.

Iwadii fihan akọroyin BBC pe awọn Dokita ti wọn n sanwo ọtọ fun gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ " Consultant" wa si awọn wọọdi ọmọde ni eyi ti wọn fidi ẹ mulẹ pe wọn yoo ṣiṣẹ ọjọ meji si awọn naa to darapọ mọ iyanṣẹlodi naa.

Agba dokita kan ti ko fẹ ki BBc darukọ oun sọ pe ẹru atubọtan iyanṣẹlodi yii n ba oun nitori pe ọpọ ẹmi ni yoo ba a rin nitori ko si itọju to pe ye tabi ti ko si owo lati lọ sile iwosan aladani.
O tun menuba iṣoro aisi dokita to to tẹlẹ nitori pe iyanṣelodi awọn olukọ Fasiti ASUU ko je ki awọn dokita tuntun kawe jade nile iwe lati ọdun to kọja lọ yatọ si ti ajakalẹ arun Covid 19.

Ni ile iwosan Mother and Child ti akọroyin BBC Yoruba tun de ni a ti ri ero bo ṣe ma n pọ bii ti tẹlẹ ṣugbọn ko si dokita nikalẹ lati da wọn lohun.
Adari ile iwosan naa, Dokita Bankẹ Oluwafemi ni awọn dokita agba ṣi wa nikalẹ lati da awọn alaisan lohun lonii
O ni oun gba pe ipe Olorun ni gbogbo iṣẹ iwosan ti awọn n ṣe ni eyi ti wọn si ti da awọn alaisan lohun loni.

Oríṣun àwòrán, others
Ki lo ti kọkọ́ ṣẹlẹ sẹyin?
Àwọn dókítà Ondo bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ
Awọn ipinlẹ Ondo ti gúnlè iyanṣẹlodi ọlọjọ pipẹ lori owo oṣu ti ijọba n jẹ wọn at'awọn ajẹmọnu mii.
Ọkan lara awọn eekan ninu ẹgbẹ dokita l'Ondo to ba BBC Yoruba sọrọ, Dokita Sanni Oriyomi Ezekiel ṣalaye pe ijọba kọ eti ikun si ikilọ awọn lo je kawon gunle iyanṣẹlodi náà.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti f'òfin de ìpéjọpọ̀ tó bá ju àádọ́ta (50) èèyàn lọ torí ọwọ́jà kejì coronavirus
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Mínísítà ètò ìròyìn nígbà kan rí Tony Momoh dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin
- 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìnì fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'
Dokita Ezekiel ni ijọba n jẹ awọn lowo oṣu lati oṣu kẹfa ọdun 2020 ki wọn to san owo oṣu kẹwaa fawọn.
O ṣalaye siwaju síi pe ijọba Ondo tun ṣadeedee san idaji ninu owo oṣu kọkanla ọdun 2020 lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣepade pọ pẹlu ijọba.
"Amọ awa dokita tako adehun ti ijọba ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ nitori awa dokita lẹgbẹ ti wa lọtọ," Dokita Ezekiel ṣalaye.
Dokita Ezekiel tun sọ pe ijọba Ondo ko ṣe ohun kan lori owo ajemonu to gba lati maa san fáwọn dokita at'awọn oṣiṣẹ eleto nitori ewu tó hu wọn nibi itọju awọn alarun coronavirus.
"Bakan naa, ijọba tun kọ láti gba awọn dokita miiran rọpo awon to ti kọwe fi iṣẹ silẹ eleyii to jẹ ki iṣẹ pọju fun wa," Dokita Ezekiel lo sọ bẹẹ.
- Seyi Makinde fi ọkọ̀ ńlá mẹ́rin dá ikọ̀ Amotẹkun lọ́lá nípìnlẹ̀ Oyo
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ ìforúkọsílẹ káàdi ìbánisọ̀rọ̀ síwájú síi
- Ọmọ ọdúnmẹ́tàdínlógún káwọ́ sẹ́yìn rojọ́ lórí ẹ̀sùn ìdúnkookò láti gbẹ̀mí ìyá rẹ̀''
- Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀
Dokita naa ni bakan naa ni ko tun si ileegbe to to fawon dokita kaakiri ipinle Ondo.
Dokita Ezekiel ni awọn ko ṣetan lati pada sẹnu iṣẹ, ayafi ti ijọba ba ṣe ojúṣe rẹ lóku.
- Ilẹ̀ Amerika ń wá olùkọ́ èdè Yorùbá, wo bí o ti lè forúkọ sílẹ̀ níbí
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
- Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀
- Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ mú àgùnbánirọ̀ di èrò iléẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kogi















