2nd wave Covid-19 in Nigeria: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti f'òfin de ìpéjọpọ̀ tó bá ju àádọ́ta (50) èèyàn lọ torí coronavirus

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Babajide Sanwo-Olu

Bi ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ kii tan leekanna lọrọ ajakalẹ arun covid-19 da bayii nipinlẹ Eko.

Lẹyin ti arun naa n fi ojoojumọ pọ si ni Naijiria papaa julọ nipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti kede pe ijọba ti fofin de ipejọpọ to ba ti ju aadọta eeyan lọ bayii kaakiri ipinlẹ naa.

Sanwo-Olu fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

Amọ, gomina ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe ofin naa ko kan awọn ile ijọsin nipinlẹ Eko ti ijọba ti sọ fun tẹlẹ pe ki wọn ma ju idaji awọn olujọsin to n maa n jọsin tẹlẹ lọ ninu gbọngan ti wọn n lo.

''Inu ijọba ipinlẹ Eko ko dun si bi ọpọ eeyan ti n tapa si ilana ati dena ajakalẹ coronavirus,'' Sanwo-Olu lo bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Gomina Sanwo-Olu sọ pe ọpọ awọn eeyan to ni gbọngan ayẹyẹ lo ti n tapa si awọn alakalẹ ofin lori ati dena covid-19.

''Eyi ni lati kilọ gbogbo awọn to ba n ṣe iruẹ lati ki ọwọ ọmọ wọn bọṣọ, bi bẹẹ kọ, wọn o fi oju wina ofin,'' Sanwo-Olu kilọ.

Àkọlé fídíò, Mckinley Erves di ẹni tọ ń ríran rí aàwọ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀

Sanwo-ọlu ṣalaye pe ''gẹgẹ bi ofin ti Aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu, ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ yii ba ṣi mọ lori yoo san owo itanran tabi ko ṣẹwọn oṣu mẹfa tabi ko ṣewọn ko si tun sanwo itanran.

Atẹjade lati ọdọ Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Gomina ni gbogbo olugbe ipinlẹ Eko lo gbọdọ maa tẹle alakalẹ ati dena ajakalẹ arun coronavirus bayii.

Àkọlé fídíò, Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu