Japanese Woman: ''Èmi àti òkú ìyá mí ni a jọ ń gbé fún ọdún mẹ́wàá ''

Tokyo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Japan ti fi panpẹ ofin mu obinrin to gbe oku iya rẹ si inu ile ninu ẹrọ amuohuntutu fun ọdun mẹwaa.

Arabinrin Yomi Yoshino to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọta ni o sọ wi pe oun ba oku iya oun ninu ile ti wọn jọ n gbe, lo ba tii mọ inu ẹrọ amuohuntutu.

O ni idi ti oun fi ṣe bẹẹ ni pe oun ko fẹ ko kuro ninu ile ti awọn jọ n gbe ni Tokyo.

Ninu ile itura kan ni ilu Chiba to sunmo Tokyo ni wọn ti fi panpẹ ọba mu arabinrin to gbe oku iya rẹ sinu ẹrọ amohuntuntun naa.

Ile Japan

Oríṣun àwòrán, others

Ikọ ọlọpaa ni ko si oju apa kankan lara oku to ti gan to wa ninu ẹrọamohuntutu naa.

Bakan naa ni ijọba sọ wi pe awọn ko lee sọ igba ti arabinrin naa ti ku tabi iru iku to pa a.

Ikọ ọlọpaa ni iwadii fihan pe ọmọbinrin naa sun oku iya rẹ ki, ko to le e gba inu amuohun tutu to gbe oku naa si.

Àkọlé fídíò, Mckinley Erves di ẹni tọ ń ríran rí aàwọ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀