Femi Falana: Ojúṣe ìgbìmọ̀ elétò ààbò pẹ̀lú gómìnà ní àfikún ọlọ́pàá sí ìpínlẹ̀, kìí ṣe ti Buhari

Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Femi Falana

Ajafẹtọ ẹni kan to tun jẹ agba amofin, Femi Falana, ti sọ oko ọrs si gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinse ati akẹẹgbẹ rẹ nipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu.

Agba amofin naa gba awọn gomina mejeeji yii ni gbolohun nitori abẹwo ti wọn se sọdọ aarẹ Buhari lọjọru lori eto aabo to mẹhẹ nipa ọsẹ tawọn ọdaran darandaran n se.

Bẹẹ ba gbagbe, gomina Makinde ati Akeredolu lo tọ Buhari lọ nilu Abuja lati beere fun afikun eto aabo to peye, nitori ọwọja awọn ọdaran darandaran to gogo nipinlẹ koowa wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Makinde, to bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade wọn pẹlu aarẹ si ni oun lo anfaani abẹwo naa lati beere fun agbekalẹ afikun ileesẹ ọlọpaa kogberegbe nipinlẹ toun.

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu Gani Adams lori ọrọ Sunday Igboho

Amọ Falana, lasiko to n takurọsọ pẹlu awọn akọroyin ni, awọn gomina yiii ni ipese eto aabo to peye wa nikawọ wọn, pẹlu ileesẹ ọlọpaa, ko si yẹ ki wọn lọ sọdọ aarẹ.

Agba amofin naa woye pe aarẹ lo n dari ileesẹ ologun nilẹ Naijiria, kii se ileesẹ ọlọpaa, ko ba si san ko jẹ pe ọdọ ajọ to n sakoso ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, ni wọn gbe ibeere wọn lọ.

Falana ni "Awọn gomina ko ni isẹ kankan lọdọ aarẹ tabi lati lọ bẹ ẹ, mo si ti sọ kan wọn loju lori ipade oore koore ti wsn n ls se kurukẹrẹ nilu Abuja.

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wò ó bí oríkì àwọn ìlú Yorùbá ṣe yọ̀ lẹ́nu ọmọ Igbo jú ọmọ onílùú lọ

Kii se ojuse aarẹ ni lati pinnu lori boya yoo fi ikọ ọlọpaa ransẹ sipinlẹ Oyo amọ igbimọ eleto aabo nipinlẹ kọọkan ti gomina jẹ olori fun lo yẹ ko pinnu lori igbesẹ naa."

Agba amofin naa ni aifi ika to tọ simu, re imu wa lara awsn ohun to n mu ki eto aabo mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Sunday Igboho kò lẹ́tọ̀ọ́ láti lé Fulani nílùú, wọ́n sì le pè é lẹ́jọ́ - Femi Falana

State of the Nation: Àwọn tí Sunday Igboho le nílùúlẹ́tọ̀ọ́ láti pèé lẹ́jọ́-Femi Falana

Gbajúgbajà agbẹjọ́rò àgbà tó tún jẹ́ ajàfẹ́tọ ọmọniyàn, Femi Falana, tí sàlàyé pé, Sunday Igboho kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé kí ẹnikẹ́ni fi ìlú sílẹ̀, ó yẹ kí ó tẹ̀lé òfin ni.

Falana sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC l‘Ọjọru lórí ipò tí Nàìjíríà wà àti èrò rẹ̀ lórí àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò tí ààrẹ Buhari yàn.

Agbẹjọ́rò àgbà náà ní "ìjọba gan kò létọ láti lé ẹnikẹni kúrò níbí tó wà nítori òfin Nàìjíríà gan sọ pé, lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí ènìyàn bá ti gbé ní ìlú kan , ó lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo ǹkan ti àwọn onílùú náà ní.

Kódà kí ènìyàn jẹ́ ayálégbé, gan ó nílò àsìkò tó tó kí wọ́n tó le kúrò nínú ilé." Ó wá rọ ìjọba ìpińlẹ̀ Oyo láti kọ́ àwọn ìbuba fún àwọn màálú.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Falana ni òun kò faramọ́ ìgbésẹ̀ Sunday Igboho rárá nítorí "ó tí tó àsìkò kí a sinmi fífí ẹ̀yà kan sọrí ìwà ìbàjẹ́, kìí ṣe ọ̀nà tó tọ.

Falana ní ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ǹkan tí ènìyàn ń fẹnusọ nìkan, bíkò ṣe pé kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ṣe agbékalẹ̀ ilé ibi tí wọn yóò tí maa tọ́jú ẹràn.

Falani ni òun kò ṣetán láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ bí kò ṣe ìjọba, gbogbo ará ìlú lóni ẹ̀tọ́ láti sọ ǹkan tó wà ní ọkàn wọ́n. Kò yẹ kí ẹnikẹni máa da ará ìlú lẹ́jọ́ fún ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá

O ní ó ṣe pàtàkì kí ìjọba feti sí ìpohùn réré ẹkún ará ìlú, kí ará ìlú tó fi ìdájọ́ sọ́wọ́ ara wọn.

Falana ní gbogbo ìṣòro tó wáyé kò ṣẹ̀yìn ìjọba Nàìjíríà, ó sì di ìgbà tí wọ́n ba bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ àwọn agbo màlùú ni ojúùtú sí ọ̀rọ̀ náà.

Gbogbo ẹni ti wọ́n bá sì ti fún ni irú ipé kúrò nílùú báyìí, irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lé pé ẹni tó pa irú aṣẹ bẹ́ẹ̀ lẹ́jọ́.

O yẹ ki Buhari yan awọn olori ileesẹ ologun sipo nibamu pẹlu ofin ni:

Femi Falana, lasiko to n sọ ero rẹ lori awọn ọga ologun ti wọn yan sipo ni o ba ni lọ́kan jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò tí kúrò nínú ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yà mẹ̀yà, kí wọ́n sì mójú tó ìwà sise deede lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹnikẹ́ni sípò.

Awọn ọga ologun tuntun

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ó ní kò tọ̀nà bí àwọn kan ṣe ń ṣe ń sọ pé ààrẹ ní àṣẹ láti yàn ẹni tó bá wù ú gẹ́gẹ́ bí olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò ní Nàìjíríà bí ó ṣe ṣe ni àná.

Falana sàlàyé pé, ó ṣe pàtàkì láti yan àwọn ènìyàn sípò ní ìlànà tí òfin là sílẹ̀.

Èyí túmọ̀ sí pé, ìhà ibí tí wọ́n ti wá ní ti ẹkùn, ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n ti wà, iye obìnrin tí ó wà níbẹ̀ tàbí ọkùnrin.

Sùgbọ́n lẹ́yìn ti wọn ti yàn wọ́n, ǹkan mẹ́ta tí ó ṣe pàtàkì tó yẹ́ kí wọ́n ṣe ní láti wádìí àwọn tí wọn ń jí owó tó yẹ kí wọ́n fi ra ǹkan ìjagun.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

O ni wọn gbọdọ tun mú ìwúrí bá àwọn ọmọogun tó wà lójú ogun, kí wọ́n si tun máa buyì fún àwọn tó kú lójú ogun, kí wọ́n sì ṣe ìtọ́jú àwọn ẹbi tí wọ́n fi sílẹ̀.

Falana ni ọ̀nà yìí nìkàn ni àwọn olórí ẹsọ́ ààbò tí wọ́n jẹ fi le kẹ́sẹ járí.