Toyin Abraham: Ẹ wo ohun báwọn ọmọ ìṣọta ṣe ya bó màmá Ire lẹ́nu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin_abraham
Awọn ọmọ adugbo ṣe ọṣẹ fun eekan osere tiata Yoruba, Toyin Abraham nibi to ti lọ ya sinima kan, to pe akọle rẹ ni Ige, laipẹ yii.
Gẹgẹ bi ohun ti oun funrarẹ sọ ninu fidio kan, awọn ọraisa naa yabo ibi to ti lọ ya sinima naa, ti wọn si n beere owo gọbọi, ki wọn to lee jẹ ki oun atawọn ikọ rẹ fi irọrun ya sinima naa.
Amọ gbogbo bi Toyin ṣe n fi ohun irẹlẹ ba awọn eeyan naa sọrọ, lo n ja si pabo, to si n rọ wọn lati gba owo lọ fi ra ọti lile.
Lẹyin ti wọn faa sọtun ati sosi, lo fun awọn janduku naa ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira lati fi lọ gbadun ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin_abraham
Amọṣa awọn janduku naa fariga pe owo naa ti kere ju fun wọn, ti wọn si ni ko tubọ gbọn ọwọ si.
Toyin Abraham wa ṣalaye fun wọn tirẹlẹ tirẹlẹ pe owo ko fi bẹẹ pọ lọwọ oun.
O ni oun ṣẹṣẹ san ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira fun awọn ti oun lo gẹgẹ bi ero, ni ibudo ti oun ti n ya sinima naa ni, eyi si lo mu kawọn janduku naa gba owo naa lọwọ rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Bakan naa lo ṣalaye pe, oun ti kọkọ fun wọn ni ẹgbẹ̀run marun naira tẹlẹ lati fi mu ẹlẹrindodo ati pe, ko tun yẹ ki wọn daamu oun mọ lori ọrọ owo.
Nigba to n salaye isẹlẹ yii loju opo Instagram rẹ, Toyin Abraham ni awọn yoo fun awọn eeyan yii ni owo, wọn yoo tun maa fapa janu pe o kere, awọn n fẹ si.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O ni irufẹ isẹlẹ yii ni awọn maa n la kọja loore koore lasiko ti awọn ba n ya sinima sugbọn awọn si nifẹ awọn eeyan naa sa.

















