Toyin Abraham: Àwọn ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham
Oni ọjọ Karun osu Kẹsan ọdun 2019 ni ayajọ ọjọ ibi gbajugbaja osere ori itage lobinrin nni, Toyin Abraham, odu si lo jẹ lagbo ere tiata Yoruba ati tawọn oloyinbo.
Toyin ti se ọpọ ere ori itage to pa ni lẹrin, kọ ni lọgbọn to si tun fun ni loye lati igba to ti darapọ mọ ere tiata naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gẹgẹ bi a se kaa loju opo ikanni agbaye Wikipedia, ọpọ iroyin ti jade nipa arẹwa obinrin ọhun eyi to wu ni lori ati eyi to ku diẹ kaato, amọ awọn iroyin miran tun wa nipa rẹ ti ẹ ko tii mọ, eyi ta fẹ fi to yin leti.
Awọn ohun to yẹ kẹ mọ nipa Toyin Abraham:
- Ọjọ Karun osu Kẹsan ọdun 1984 ni wọn bi Toyin Aimakhu, to wa pa orukọ da di Toyin Abraham bayii si ilu Auchi nipinlẹ Edo, to si pe ẹni ọdun marundinlogoji lọjọbọ
- Olusọagutan ni baba Toyin to ti di oloogbe, to si gba Alọrun gbọ gidigidi
- Ilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Ọyọ ni Toyin ti se kekere rẹ, to si lọ sile ẹkọ Gbogbonse Poly Ibadan nibi to ti kẹkọ jade pẹlu oye Diploma agba(HND) lẹka imọ nipa katakara ọja( Marketing), ko to dara pọ mọ isẹ tiata
- Ọdun 2003 ni Toyin Abraham bẹrẹ isẹ tiata lasiko ti ilumọọka osere tiata kan Bukky Wright lọ silu Ibadan lati lọ ya sinima kan, to si se kẹrẹ-kẹrẹ di ilumọọka onitiata
- Toyin ti kopa ninu ọpọ ere onise bii Ayitalẹ, Alani Baba Labakẹ, Ẹbi mi, Okafor's law, Ghost and the tout, toun naa si tun ti gbe awọn ere tiẹ jade bii Alakada eyi ti wọn fi n se adape orukọ fun-un
- Bakan naa lo ti gba ọpọ ami ẹyẹ to nii se pẹlu ere ori itage, to si tun maa n ba awọn oloselu se ipolongo ibo
- Bakan naa ni osere tiata yii se igbeyawo akọkọ pẹlu akẹẹgbẹ rẹ kan, Adeniyi Johnson lọdun 2013 ti wọn si se iyawo oloruka ni Ikoyi
- Ọdun meji pere si ni awọn mejeeji lo bii tọkọ taya, ki ipinya to de saarin wọn lọdun 2015 eyi to ya ọpọ ololufẹ rẹ lẹnu, ti iroyin si tun gbe nigba kan pe ohun ati gbajumọ kan, Seun Ẹgbẹgbẹ ni ifẹ ikọkọ
- Iroyin kan to wa mu inu awọn ololufẹ Toyin dun julọ ni eyi to gba ori afẹfẹ kan pe oun ati akẹẹgbẹ rẹ, Kọla Ajewọle ti se mọmi n mọ ọ, ti wọn si setan lati di tọkọ-taya
- Ko ju ọjọ diẹ lẹyin eyi, eyiun lọjọ Kẹẹdogun osu Kẹjọ osu Kẹjọ ọdun 2019 ni ayọ gba ilu kan pe Toyin Abraham bi ọmọkunrin tuntun jojolo, ti aworan oun ati ọmọ si gba ori ayelujara kan, to si pe orukọ rẹ ni Ire.
Ko ti pe osu kan to bimọ tuntun naa ni oun naa tun se ọjọ ibi yii, ta si n gbadura fun pe ẹmi rẹ yoo se pupọ ọdun laye.








