Gani Fawehinmi: Òní ló pé ọdún mẹ́wàá ti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni náà jadẹ́ láyé

Gani Fawehinmi

Oríṣun àwòrán, @MichaelSolanke3

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iku n pani, ilẹ n jẹyan. Ọjọ Karun osu Kẹsan ọdun 2019 lo pe ọdun mẹwa geerege ti ilumọọka ajafẹtọmọoniyan nii, Gani Fawehinmi jade laye.

Ọjọ Karun, oṣu kẹsan, ọdun 2009 ni Fawehinmi dagbere faye lẹyin to ti ba aisan jẹjẹrẹ wọya ija fun igba diẹ.

Loju opo Twitter, ọrọ ikini lorisirisi ati iranti nipa igbe aye rẹ ni awọn eeyan Naijiria n fi sita.

Ninu fọnran fidio yi ti EiENigeria fi sita, a ri bi Fawehinmi ṣe n gbejọro niwaju igbimọ Oputa ti ijọba gbe kalẹ, lati yẹ awọn ibaje to waye lorileede Naijiria wo.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ẹbi, ọrẹ ati awọn ololufẹ ni wọn n ṣeranti Fawehinmi lonii.

Pupo lo n ṣe eemọ ohun ti Fawehinmi ko ba sọ nipa orisirisi nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria lọwọlọwọ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Tani Fawehinmi jẹ ninu itan Naijiria?

Ọmọ bibi ilu Ondo ni Gani Fawehinmi, ta si bi ni ọjọ Kejilelogun oṣu Kẹrin ọdun 1938.

Ile ẹkọ Hoborn College lo ti kẹkọ gboye nipa imọ ofin lọdun 1961.

Aworan Gani Fawehinmi

Oríṣun àwòrán, @AbdulMahmud01

Laarin ọdun 1971 si 1973, o jẹ oye alukoro ẹgbẹ awọn agbẹjọro Naijiria.

Nigba aye rẹ, ọpọ igba ni Gani Fawehinmi ṣẹwọn lori pe o n ja fun ẹtọ ọmọniyan paapa julọ labẹ ijọba ologun Naijiria.

Ṣaṣa ni ọgba ẹwọn ti ko tii gbalejo Gani Fawehinmi, eyi to mu ki awọn eeyan Naijiria fun ni oye ‘agba ajafẹtọ mẹkunnu’, Senior Advocate of Nigerian Masses.

Gani Fawehinmi

Oríṣun àwòrán, @NuhuRibadu

Àkọlé àwòrán, Gani Fawẹinmi kó ipa to kúrò ni kèrémí fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ iṣejọba alágbádá ni Naijiria

Ọdun 2001 ni wọn fi joye agba ọjẹ amofin ti a mọ si Senior Advocate of Nigeria,SAN da Fawehinmi lọla.

A nwa n gbadura pe ki Ọlọrun dẹ ilẹ fun ẹni re to lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: