#Revolution Now: Ara ló ń ta ìjọba àpapọ lórí ìfèhọnú hàn ní Naijiria

#Revolution Now
Àkọlé àwòrán, Comrade Sulaiman Adeniyi ti ni o lodi si ofin bi ijọba se n tako itusilẹ Ọmọyele Sowore to ti wa ni ahamọ DSS.

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan ti ko din ni metalelaadọta ni wọn ti ṣetan bayii lati fi ehọnu han ni Ọjọ Karun un, Oṣu Kẹsan, ọdun yii.

Oludari fun alakoso egbẹ ajafẹtọ Coalition of Human and Civil Rights Organizations(COHCRO) Comrade Sulaiman Adeniyi lo sọ eyi lasiko to n ba ikọ ile isẹ BBC Yoruba sọrọ.

Comrade Adeniyi ni gbogbo eto lo si ti to fun ifẹhọnu han naa latari ifiyajẹni lọna aitọ ti ijọba apapọ gunle fun Oludari ikọ Revolution Now, Omoyele Soworẹ.

Sulaiman Adeniyi tẹsiwaju pe, yoo tun jẹ ọna kan pataki lati ṣe iranti ọdun kẹwa ti oloye Gani Fawehinmi di oloogbe.

Ninu ọrọ rẹ, Sulaiman Adeniyi sọ wi pe, ko si ohun ti yoo yẹ ẹ ọjọ ifẹhọnu han lati ma se waye, nitori mani gbagbe ni yoo jẹ.

Oludari fun alakoso egbẹ ajafẹtọ Coalition of Human and Civil Rights Organizations(COHCRO) fikun pe ara lo n ta ijọba apapọ nitori aiṣe deede wọn pelu ara ilu, nipa pipese ohun to tọ, to si yẹ fun mutumuwa.