Dangote-BRT Accident: Lasema ní ìjánu ọkọ̀ Dangote tó já ló fa ìjàǹbá náà

Oríṣun àwòrán, Lasema
Ilé iṣẹ́ tó ń móju tó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwírì nípinlẹ̀ Eko (LASEMA) ní ọkọ̀ akẹ́run Dangote tó kún fún simẹnti, ní ìjánu rẹ̀ dédé já, tí o si lọ kọlu ọkọ èrò BRT to kó èrò ọgọta lópóna Ikorodu.
Ọkọ̀ BRT pẹ̀lú nọmbá LSR-228 XS ọhun to forisọri pẹlu ọkọ simẹnti ní gbogbo èrò inú rẹ̀ ní ifarapa kan tábi òmiràn ti ẹsẹ̀ dẹ́rẹ́bà náà sí gé pátápátá.
Apapọ awọn ero to fara gbọgbẹ ninu ijamba naa ni mọkandinlọgọta, ti eeyan kan si gbẹ mi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà ló ṣiṣẹ́ takò mí ní Ireland kí ń má baà wọlé ìbò Káńsélọ̀ - Yemi Adenuga
- Láti January lọ, gbogbo ẹni tó bá ra ọjà lórí ayélujára yóò máa sanwó orí - FIRS
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Irọ́ ńlá! Ẹgbẹ́ IPOB ò tako Ààrẹ Buhari ní Japan- Iléeṣẹ́ Ààrẹ
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
- Irọ́ ló pa, a kò mọ̀ ọ́ rí tàbí fún ọ ní ₦13m - APC tako afurasí ajínigbé
Gẹ́gẹ́ bi olùdari LASEMA Osanyintolu Oke ṣe sọ, kò sí ẹni ti kò farapa nínú ọkọ náà àfi ọmọbinrin kan ló pàdánu ẹmi rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Lasema
O fí kun pé, gbogbo àwọn osisẹ eleto alabò àti àwọn ẹṣọ́ ojú pópó pátápátá lo ti péju síbi ti isẹlẹ naa ti waye, láti ri dáju pé awọn to farapa ri ìtọ́ju àti láti mú ìgbòkegbodo ọkọ̀ rọrùn lágbègbè náà.








