U.S. Visa: Àwọn ọmọ Naijiria yóò má a san àfikun owó láti wọ Amẹrika

Asia ilẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, @ClemsonTigerNet

Orilẹede Amerika ti polongo afikun iye owo iwe irinna (Visa) fun ẹnikẹni lati orilẹede Naijiria, to ba fẹ wọ ilẹ Amerika.

Ninu atẹjade ti orilẹede Amerika fi lede, lati ọjọ kọkandinlọgbọn, Osu Kẹjọ ni afikun owo yoo ba iye owo ti awọn ọmọ Naijiria n san lati wọ ilẹ Amerika.

Wọn ni eleyii ba ofin ilẹ Amẹrika mu nitori iye ti ijọba Naijiria n gba lọwọ awọn ara ilẹ Amerika to ba fẹ wọ orilẹede Naijiria ju iye owo ti orilẹede Amerika n gba ni ọwọ awọn ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ilẹ Amerika ni ọpọ igba ni awọn ti kesi ijọba Naijiria lati se atunse lori iye owo ti wọn n gba lọwọ awọn ọmọ ile Amẹrika to ba fẹ wọ orilẹede Naijiria, eleyii ti wọn kọ ẹti ikun si.

Awọn ero ni papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, @ClemsonTigerNet

Idi niyi ti orilẹede Amẹrika naa se f gba ẹsan lara Naijria, to si jẹ pe ileesẹ asoju ilẹ Amẹrika nikan ni wọn yoo maa san owo afikun owo ti wọ̀n fi n gbẹsan ọhun, ti wọ̀n pe ni ‘reciprocity fee’ naa si, kii se ile ifowopamọ kankan.

Afikun iye owo ti wọn n pe ni (Reciprocity Fee) re e:

  • B1$110
  • B2$110
  • B1/B2$110
  • F1 $110
  • F2$110
  • H1B $180
  • H4$180
  • I$210
  • L1 $303
  • L2$303
  • R1 $80
  • R2$80