Gboyega Oyetola: A ṣetán láti pèsè ọkọ̀ oun ìjà fún ilẹ Yorùbá

Oyetọla

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ìjọba ipnlẹ Òsun ní kò sí òṣìṣé tí kò ní gba owó oṣu rẹ pé ní Ipínlè Ọsun .

Gomina lpinle Osun, Gboyega Oyetola ti ṣalaye wi pe ijọba ipinlẹ Osun ti ṣe tan lati ṣe atilẹyin fun ipenija to ba eto aabo ni ilẹ yii.

Gomina Oyetola sọ siwaju wi pe ọkọ ijagun ti ko din ni ogun ni ijọba ipinlẹ naa yoo fi ṣe atileyin latari idasilẹ ajọ tuntun fun eto abo ilẹ Yoruba.

Oyetọla sọ ọrọ yii lasiko ayẹyẹ ọdun mejidinlọgbọn ti wọn da ipinlẹ naa silẹ,O ni eto aabo ilẹ Yoruba jẹ Ohun logun.

Gẹgẹ bii alaye re, O ni, irọrun igi ilẹ Yoruba ni irọrun ẹyẹ ipinlẹ Osun, lojuna lati daabo bo dukia ati ẹmi awọn eniyan ilẹ Yoruba lapapọ.

Ìpinlẹ Òsun pé ọmọ ọduń méjìdínlógbọn, àsantán owó osù ti bèrè!

Gomina lpinle Osun, Adegboyega Oyetola ti ba awọn ọmọ ipinlẹ naa yọ latari pipe ti ipinlẹ naa pe ọdun mejidinlọgbọn.

Ninu ọrọ rẹ si awọn ọmọ ipinlẹ naa ni ọjọ Aje nibi ti o ti salaye wi pe, ayẹyẹ naa pe fun ibara ẹni yọ, sugbọn ni pẹlẹkutu ni ljoba yoo sẹ.

O sẹ alaye wi pe, arọ ipinlẹ naa fẹ jo,sugbọn ẹsẹ ni ko ni, latari aisi owo lati fẹ ayẹyẹ naa loju.

Nigba ti oun gbe osuba kare fun awọn asaaju lpinlẹ naa, ni pataki, awọn gomina ana ninu eyi ti o ka ijọba ana kun ti o pe ni'' ifẹsẹ mulẹ to muna doko''ninu eyi ti awọn to ku n gunle.

Oyetọla ko ṣai fẹnu ba a wi pe awọn eniyan ipinlẹ naa jẹ akinkanju, olufẹ aṣa ati ẹni ti igbagbọ wọn ranmọ oye awón baba n la wọn fun nini lpinlẹ ''Ọmọluabi''

Gomina naa sọ wi pe gbogbo eto isejọba lpinlẹ naa lo da lori oun ti ara ilu n fẹ. ti o si ṣe afihan rẹ nigba ti o ṣe abẹwo si llu kọọkan lati mọ oun ti wọn fẹ.

Ko ṣai gbe ọrọ rẹ lẹsẹ pẹlu ipa ti ajọ United Nations ti o wa fun idagbasoke ilu ti ko lori lpinlẹ naa.

Oyetọla ṣalaye siwaju sii pe,ijọba oun yoo maa san ẹkunrẹrẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ deede.

Gomina lpinle Osun naa yoo tun kọ si ile iwe, ati lati tun ọpọlọpọ ṣe. O ni kikọ yara ikawe oloju mẹrin,marun un, ati bẹẹbẹẹ lọ ko ni jẹ iṣoro fun ijọba Oun.