Ondo Murder: Awọn ọlọ́pàá kò tíì mọ ibi tí wọn sin òkú ọmọ náà sí

testimony

Oríṣun àwòrán, sunshinetruth.com.ng

Arabinrin kan ti wọn fi ẹsun kan pe oun ati ọkọ rẹ lu ọmọ wọn pa, ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii.

Iroyin sọ pe Testimony, ọmọ ọdun mẹrin ti wọn lu pa, ni wọn gbe lọ si ileewosan ijọba to wa nilu Akurẹ lọjọru ọsẹ to kọja pẹlu oniruru apa lara rẹ.

Nile iwosan si ni awọn dokita ti jẹ ko ye wọn pe oku ni ọmọ naa, ki wọn to gbee de ileewosan.

Lati igba naa ni awọn ọlọpaa ti bẹrẹ si ni tọ ipasẹ tọkọ-taya naa, ṣugbọn ti wọn lọ fi ara pamọ si ilu Ikarẹ Akoko.

Gbogbo ilakaka awọn ọlọpaa lati mu wọn ni ilu Ikarẹ lo ja si pabo pẹlu bi awọn iroyin kan ṣe sọ pe, awọn eeyan ilu naa ko gba awọn ọlọpaa laaye lati ṣe iṣẹ wọn, nigba ti wọn lọ lati mu tọkọ-tiyawo naa.

Awọn osisẹ Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Bi o tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ni ko si ohun to jọ bẹẹ, amọṣa wọn ni arabinrin naa ti wa ni ọdọ ọlọpaa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko tii ri oku ọmọde naa ati wi pe, o ṣeeṣe ki awọn lọkọlaya naa ti sin oku rẹ.