Ìjọba Ọyọ: Olówó nìkan kọ́ ni ìdájọ́ iléẹjọ́ yóò máa gbè ní Ọyọ

Ẹlẹwọn kan na ọwọ latinu ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, @Lagostalks913

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fi ọwọ idaniloju sọya pe latri akoko yii lọ, oun yoo maa gbe igbesẹ lati mu adinku ba ajaga ẹru ẹjọ to wa lawọn ileeẹjọ, ti wọn yoo si maa yanju awọn ẹjọ pẹlu iyara kankan.

Kọmisana feto idajọ ati agbẹjọro agba nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Oyelọwọ Oyewọ lo fi ọwọ idaniloju yii sọya lasiko to n bawọn akọroyin jẹwọ ni ọọfisi rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oyewọ salaye pe bakan naa ni ijọba Ọyọ ti setan lati se atunto awọn ọgba ẹwọn wa, ti aparo kan ko fi ni ga ju ọkan lọ, ti idajọ yoo si maa waye lai fi igba kan bo ọkan ninu tabi se oju saaju.

Oyewọ tun ni aayan tun ti n lọ lati ri daju pe pepele kan wa fun atunse awọn ẹlẹwọn, ti ayipada yoo si tun ba ero araalu ti wọn gba pe awọn olowo ati ọlọrọ nikan ni idajọ ileejọ n gbe.

Ọgba ẹwọn to kun akunfaya

Oríṣun àwòrán, @Lagostalks913

"A fẹ se agbekalẹ awọn ilana ofin ti ẹka eto idajọ yoo gbajumọ. Fun apẹẹrẹ, eto sisi oju aanu wo awọn ẹlẹwọn yoo bẹrẹ, ta si se atunto aye wọn. Gbogbo ẹlẹwọn to ba si gba itusilẹ lati ipasẹ oju aanu yii, ni ko tun ni pada lọ sọgba ẹwọn mọ."

Oyewọ fikun pe ijọba fẹ gbe igbesẹ naa nifọwọkọwọ pẹlu awọn asaaju ẹsin, awsn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lawujọ ati awọn ẹgbẹ alaanu gbogbo.