ALGON: 35% la fẹ́ kíjọba àpapọ̀ máa pín bíi owónàá fún ìjọba ìbilẹ̀

Asia Algon

Oríṣun àwòrán, Algon

Àkọlé àwòrán, A kò lé fáramọ bí ẹ sé fẹ́ maa pín owó Nàìjíríà: ALGON

Agbarijọpọ ẹgbẹ́ awọn ìjọba ìbílẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (ALGON), tí ké sí ìjọba apapọ̀ pé, ìlànà ti wọ́n fẹ́ máà fi pín owónàá oṣooṣù ko tẹ́ àwọn lọ́rùn rárá, àfi kí wọ́n máa pín ni ìdá márùndínlógójì nínú ìdá ọgọ́rùn.

Ẹgbẹ́ náà kọ ìdá mẹ́tàlélógun ti àwọn gómìnà ti ṣètò fún wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí gbé pééli díẹ̀ sí ìdá ogun o lé diẹ̀ ti wọ́n ń gba tẹ́lẹ̀ lọ.

Nínú ìpàdé wọn ní àwọn gómìnà mẹ́rẹ̀rìndílógójì ti sọ nínú ìbéère wọ́n pé, ìdá mejilélógóji ni àwọn fẹ́ máà gba, èyí to jìnà sí ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tí wọ́n ń gbà tẹ́lẹ̀.

Èyí ló mú kí wọ́n dábàá pé kijọba apapọ ṣe adínkù owó tó ń pínfun ara rẹ, eyi to jẹ́ ìdá méjìléláàdọ́ta, ko si sọ di ìdá mẹ́tàdínlógójì.

Sáájú ní alága àjọ tó n rísi bí ìjọba ṣe n setò owó (RMAFC) Elias Mbam, tí ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó ti yóò jòkó láti jíròrò lórí bi wọ́n yóò ṣe maa pin owo sí ipele ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Mbam ní ìpínnu ìlànà ti àwọn fẹ́ gúnle yìí ni wọ́n ti dábàá tẹ́lẹ̀ láye Obasanjo, èyí ti ìjọba ìbilẹ̀ yòó ma gba ìdá mẹ́tàlélógun.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti Punch fún ààrẹ gbogbo-gboo ẹgbẹ́ ALGON, ọgbẹ́ni Alabi David sàlàyé pé, o ti wá di dandan bayìí láti gba iyé owó yìí, nítori ìṣẹ́ ribiribi tí ó ti wà lọ́rùn àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ báyìí kii se kekere.