Ta ni Ọjọgbọn Adebanji Akintoye tó borí Tinubu láti di olórí àwọn Yoruba?

Akintoye

Oríṣun àwòrán, @Alternative Africa

Àkọlé àwòrán, Agba ọjẹ Alakada to wọnu oṣelu

Ọjọgbọn Adebanji Stephen Akintoye lo jawe olubori ninu idibo ti wọn ṣe fi yan olori tuntun fun iran Yoruba.

Assembly of All Yoruba Groups, Worldwide lo ṣeto idibo naa ni Ibadan lẹyin ti wọn yan Oloye Bola Tinubu àti Ọjọgbọn Adebanji Akintoye ki wọn to dibo.

Ninu idibo naa ni Akintoye ti jawe olubori to si di olori YorubaẸgbẹ́ Ilẹ̀ Yorubà gba Aṣíwájú tuntun!

Akintoye lo rọpo oloogbe Abraham Adesanya to n dari iran Yoruba to doloogbe loṣu kẹrin, lọdun 2008.

Àkọlé fídíò, Seun Fakorede di kọmísánà ní ìpínlẹ̀ Oyo

Ta ni Ọjọgbọn Adebanji Akintoye?

A bi Adebanji Akintoye sile alade lọdun 1935.

O jẹ onkọwe, onimọ ninu itan ati alakada.

Adebanji Stephen Akintoye lọ sile iwe Emmanuel Primary school Ado Ekiti, ati Christ's School ni Ado Ekiti laarin ọdun 1951 si 1955.

O ka nipa itan ẹda ni University College (Overseas College of the University of London) ni Ibadan to ti wa di fasiti ọlọgba ẹranko ti sanmọnti gbe dun ilẹ lọdun 1956 si 1961.

Ọjọgbọn Adebanji gba oye ọmọwe (Ph.D) lori imọ kikun ninu itan lọdun 1966 ni Fasiti Ibadan.

O ṣiṣẹ olukọni ni Fasiti olódòdó Ifẹ, to ti di Obafemi Awolowo University, Ile Ifẹ nibi to ti gba oye ọjọgbọn to tun ti ṣe adari ẹka ẹkọ nipa ilẹ Adulawọ (Institute of African Studies) lati ọdun 1974 si 1977.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Joe Igbokwe kò yẹ́ fún ipò ti wọ́n fún nípìnlẹ̀ Eko - Babatunde Gbadamosi

O ṣiṣẹ olukọni nipa Itan eniyan ilẹ Adulawọ ni Fasiti guusu Florida iyẹn South Florida University ni Tampa ni Florida ni orilẹ-ede America.

Lẹyin eyi o tun ṣiṣẹ olukọni ni Montgomery County Community College PA ati ni Eastern University St Davids ni Pennsylvania ni America.

Akintoye ti kọ iwe apilẹkọ loriṣiiriṣii yatọ si orí kan ninu iwe ka to sọ awọn jọọna ati awọn beba iwe iṣẹ akanṣe ti wọn ti gbe sita kaakiri agbaye.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀dọ́ Naijiria ti sọ̀rọ̀ síta lórí ohun ti wọ́n ń retí lọ́dọ̀ minista tuntun

Ta ni Akintoye ninu oṣelu Naijiria?

Adebanji Akintoye ti ṣe senetọ Naijiria ri.

O ṣiṣẹ aṣojuṣofin lọdun 1979 si 1983 lasiko iṣejọba alagbada keji nigba ti o kopa ribiribi ninu iṣelu Naijiria.

Ondo atijọ ni ọjọgbọn yii ṣoju fun nile igbimọ aṣojuṣofi lasiko yii.

Ṣe o ti gbọ nipa Akintoye Alakada?

Ọjọgbọn Akintoye jẹ ọkan lara awọn agba ọjẹ alakada to n ṣiṣẹ lori itan iran Yoruba.

O ti di ipo to le ni mẹtadinlogun mu ni fasiti kaakiri Naijiria ati loke okun.

Iṣẹ to ṣe gbẹyin ni iwe to gbe jade to pe ni Itan Iran Yoruba nibi to ti ṣe iwadii to tako awọn nkan ti wọn gabgbọ nipa iran Yoruba tẹlẹ lai ni ẹri to peye.

Ojọgbọn yii fẹyinti, o si fi ilẹ America ṣe ibujoko fun ọpọlọpọ ọdun ko to o pada waye

Iwe tuntun to ṣe yii gbe iwadii tuntun jade lori ero Samuel Johnson (1846-1901) nipa ilẹ Arab bii orisun Yoruba. ati iṣẹ Ulli Beier.

Wale Adebanwi, ọkan ninu awọn to ṣe atupalẹ iwe tuntutn yii rii pe o sorọ kikun nipa agabra Ile Ifẹ lori Oyo ile ati Oyo oko.

Iwe yii lo tun ti sọ nipa itan iwasẹ to da Yoruba silẹ nibi ti Akitoye ti tumọ Ile Ifẹ nibi ti ojumọ ti n mọ waye.

Àkọlé fídíò, Awa Bike wà fún eré ìdárayá àti díndín èéfín agbègbè kù