FRSC dá N443,180 padà fún ẹbí ẹni to ní ìjàmbá mọ́tò

Oríṣun àwòrán, @FRSC
Eyi ko jẹ tuntun pé a n da owo pada fun ẹbi awọn to kagbako ijamba ọkọ -FRSC
Ajọ ẹṣọ oju popo ni Naijiria, Federal Road Safety Corps (FRSC) ni ipinlẹ Kebbi ni awọn ti da owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọta o le ni irirnwo naira pada fun ẹbi awọn to ni ijamba ọkọ.
Ogbẹni Abayọmi Asaniyan to jẹ oludari ẹka ajọ FRSC ni ipinlẹ Kebbi ni ariwa Naijiria lo sọ eyi di mimọ fawọn oniroyin nipinlẹ Kebbi.
O ni awọn ri owo yii lọna meji nibi ijamba ọkọ to ṣẹlẹ ni Birnin Kebbi ati ni ijoba ibilẹ Argungun nipinlẹ Kebbi.
Abayọmi ni ikọ ẹṣọ FRSC ri ẹgbẹrun lọna irinwo le ni ọgọjọ naira nibi ijamba ọkọ to ṣẹlẹ ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ ọdun yii ni opopona marosẹ Argungun si Birnin Kebbi.
Nigba ti wọn wọn ri ẹgbẹrun mẹtalelogoji o le ni ogun naira ni ijamba ọkọ to waye ni opopona Cemetry atijọ ni Birnin Kebbi.
Oga agba FRSC yii ni gbogbo owo naa ni ajọ FRSC ti da pada fun awọn ẹbi awọn ẹni naa lẹyin iwadii ti o yẹ.
O gba awọn oṣiṣẹ FRSC kaakiri Naijiria nimọran lati maa fi ootọ inu ṣiṣẹ bii ti awọn ọmọ abẹ oun.

Oríṣun àwòrán, @FRSC
Abayọmi ni o tọna ki wọn maa ṣe akọsilẹ ohun gbogbo ti wọn ba ri nibi ijamba ọkọ loju popo ki wọn si maa koo fun awọn ẹbi awọn ti ọrọ kan lasiko.
Bakan naa lo kilọ iwa ibajẹ fawọn oṣiṣẹ pe oju gbogbo n wa lara àwọn oṣiṣẹ ti ọwọ wọn ko ba mọ to.
Ni ipari ọgbẹni Abayọmi parọwa fawọn arinrinajo ati awakọ lati ṣe pẹlẹ loju opopona nitori pe ẹmi ko laarọ.
- Wo ipò tí Buhari fún Faṣọla, Lai Mohammed, Saraki àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
- Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí àwọn ti Sanwo Olu yàn sípò
- Àwọn ọmọ Yorùbá wo ni mínísítà ní ìjọba Buhari?
- Ike Ekweremadu, igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ́ rí èèmọ̀ he nilùú Germany!
- Ọlọ́pàá Germany ti mú àfurasí mẹ́rin nínú àwọn tó kọlu Ekweremadu ni Germany














