Wọ́n fi ẹyin adìyẹ lé Ike Ekweremadu, kúrò níbi àṣeyẹ kan ní Germany

Oríṣun àwòrán, Ike Ekweremadu
Ẹyin eeyan wa, aṣe nnkan n ṣẹlẹ niju ara etile o gbọ ni. Boya wọn si gbọ, wọn fi mọra ni awa o mọ o.
Ẹ n bi mi pe ki lo ṣẹlẹ?
Igbakeji aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ, Sẹnetọ Ike Ekweremadu lawọn ọmọ ẹya apa ila oorun gusu orilẹ-ede Naijiria kan din dundu iya fun lọjọ Abamẹta ni ilu Nuremberg lorilẹ-ede Germany.
- 'El-Zakzaky lè má láńfààní láti lọ gba ìtọ́jú mọ́ lókè òkun'
- Ayédèrú Ọ̀ṣun ni wọ́n ń bọ lónìí, kìí ṣe ojúlówó - Bàbá Ọlọ́ṣun tún figbe ta
- Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti
- Buhari júwe ọ̀nà ilé fún Obono-Obla lórí ẹ̀ṣùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí
- Facebook fi kọ́kọ́rọ́ ti àwọn ojú òpó ayédèrú ìròyìn léde Yorùbá àti Igbo
Gẹgẹ bi iroyin ti agbọ ṣe sọ, nṣe ni wọn fi iwe pe Sẹnetọ Ekweremadu si ibi eto nla kan ti awọn ọmọ ẹya igbo to n gbe ni ilu naa gbe kalẹ.
Gẹgẹ bi ipe ti wọn pe e, oun ni yoo jẹ alejo pataki nibi eto naa.
Amọṣa, ki a maa deena pẹnu, kaka ki wọn bu ẹyẹ fun un gẹgẹ bi alejo pataki, nṣe ni wọn yẹyẹ aṣofin agba naa.
Koda, ẹyin tutu ni wọn ju luu, wọn ko si tilẹ jẹ ko ri aaye wọle debi pe yoo roju raye ṣe alejo pataki ti wọn pee fun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Awọn amugbalẹgbẹ ati ọrẹ rẹ kan to ba ikọ BBC sọrọ fi idi rẹ mulẹ, amọṣa wọn bu ẹnu atẹ lu iwa naa.












