Àwọn èèyàn sọ́rọ́: Ẹ máà ṣi Fayemi túmọ̀ lórí àṣẹ tó pa nípa sísọ Yorùbá

KAYODE fAYEMI

Oríṣun àwòrán, facebook/Government of Ekiti State, Nigeria.

Ni ọjọ Aje ni ijọba ipinlẹ Ekiti kede pe ko saye oyinbo sisọ mọ lawọn ibi eto to ba jẹ abinibi abi ti ibilẹ.

Ninu ọrọ ti gomina Fayẹmi fi ṣọwọ si ibi ipade kan lori aṣa ati iṣe lo ti kede eyi.

Lati igba ti o si ti jade si eti araye ni ọpọ awọn eeyan nilẹ yii ati loke okun ti n fi ero wọn han lori igbesẹ naa.

Alagba S.B. Bakare to jẹ Ọga agba ileewe girama kan ṣalaye pe igbesẹ ti Gomina Fayẹmi fẹ gbe naa yoo nira diẹ.

O ni pẹlu bi aye ti ṣe di ti ayelujara ti ọwọ si ti n kan owo nipa okowo, igbeyawo atawọn nnkan miran, sisọ ede Ekiti tabi ede Yoruba nikan yoo fa ọpọlọpọ gbọnmisi omi o to ati ede-ai-yede.

"Kini yẹn ko lee fi bẹẹ rọgbọ.

Bi wọn ṣe fẹ ki a maa sọ Yoruba apapandodo yii, awọn ti wọn wa ni ilu yẹn ti wọn jẹ ede mii, bawo ni wọn ṣe fẹ maa ba ara wọn sọrọ.

O lee ṣeese ni ilu wọn lọhun ṣugbọn to ba gbe e lọ si ile aṣofin yoo nira diẹ.

Yoo fa wahala silẹ bi wọn ba kan an ni dandan.

Bawo ni wọn yoo ṣe ṣee to ba jẹ wi pe eto ti wọn n ṣe jẹ eto ẹya Ibo tabi Hausa tabi ede miran ni ṣugbọn ti wọn wa ni ipinlẹ naa.

Ṣe iyẹn ko ni fa wahala ṣa. O gbọdọ ṣọra ṣe lori rẹ."

Bakan naa, ninu ero tirẹ, ọmọwe Ademọla Adetokun to jẹ aarẹ tẹlẹ fun ẹgbẹ Akọmọlede Yoruba ni aṣiwi o to aṣisọ lori ọrọ naa ati pe kii ṣe gbogbo eeyan ni ọrọ naa kan 'bikoṣe awọn ọmọ Ekiti nikan lati lee ran ede ati aṣa Yoruba lọwọ."

O ni ko si ohun to buru nibẹ ti awọn eeyan ba gbọ gomina ni agbọye nitori idagabsoke ede ati aṣa ṣe pataki lasiko yii.