2023 Elections: Shehu Sani ní àfàìmọ̀ kí Yorùbá àti Igbo má kùnà nínú ìbò ààrẹ ọdún 2023

Oríṣun àwòrán, Facebook/Shehu Sani
Yoruba ati Ibo le kuna lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2023 ti idibo gbogbgbo miiran yoo tun wa ye.
Sẹnẹtọ to wa lara awọn ile igbimọ aṣofin kẹjọ, Shehu Sani lo fọrọ yii lede lọjọ Abamẹta.
Sẹnẹtọ tẹlẹ ri sọ pe ti Yoruba ati Igbo ko ba fẹnu ko lori ẹni ti yoo apa guusu orilẹede Naijiria, afai mọ ki ipo aarẹ maa bọ mọ wọn lọwọ lọdun 2023.
- Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield
- Rẹ́rẹ́ run! Crystal Palace pàkúta sí gaàrí Manchester United ní Old Trafford
- Wilfred Ndidi, ọmọ Nàìjíríà pa iná ògo Chelsea ní Stamford bridge
- Manchester United dáná sun Chelsea bi ẹràn àgbò iléyá
- "Ojú wa rí tó ní Egypt, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ wá lọ́mú, ni wọ́n ń gbá wa ní ìdí"
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
- Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Mercy Aigbe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson
- Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo
Shehu Sani lootọ ni ko ni boju mu ki aarẹ Naijiria tun wa lati apa ariwa orilẹede yii ninu idibo ọdun 2023, amọ o le ṣẹlẹ bẹẹ ti awọn eeyan to wa lapa ila oorun ati iwọ oorun guusu ko ba fimọ sọkan.
O fikun ọrọ rẹ pe oun gbagbọ ninu pinpin ipo aarẹ lati apa kan si omiran kaakiri Naijiria.
Sani aigbọra ẹni ye laarin Yoruba ati Igbo lori oludije ti ṣoju guusu Naijiria ninu ibo aarẹ ọdun 2023 le fun awọn eeyan ariwa lanfaani lati tun jẹ aarẹ lọdun 2023.
Aarẹ Muhammadu Buhari to n ṣoju apa ariwa yoo ti lo ọdun ,mẹji lori laeefa to ba pari saa keji rẹ lọdun 2023.








