Chelsea vs Leicester city: Lẹ́yìn àjẹranjú ìyà lọ́wọ́ Man United àti Liverpool, Wilfred Ndidi tún pa fìtílà Chelsea ní Stamford bridge

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo nnkan lo lọ lodilodi ni ibi ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Leicester city ni ọjọ Aiku. Ko ṣe maa sọ ni pataki ati jawe olubori ni ifẹsẹwọnsẹ yii fun ikọ Chelsea lẹyin ti wọn ti jẹ ajẹranju iya lọwọ Manchester united ati Liverpool laarin ọjọ mẹrin sirawọn.
Ifẹsẹwọnsẹ naa ni akọkọ ti Chelsea yoo maa gba niwaju awọn alatilẹyin wọn ni saa liigi 2019/2020.
Ohun si tun ni akọkọ fun oluksni wọn tuntun, Frank Lampard ni Stamford bridge to jẹ ibuba ikọ Chelsea. Nitori naa ere ati jawe olubori ni wọn sa wọ ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ṣugbọn ṣe wọn ni Satide ti yoo dun, ọjọ Jimọleyan tii mọ. Ọrọ bẹrẹ si ni ri bakan nigba ti oludari ifẹsẹwọnsẹ naa, Graham Scot ti ha sinu sunkẹrẹ fa kẹrẹ ọkọ ni opopona M40 eleyi to mu ki o pẹ de ibi ifẹsẹwọnsẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oliver Langford ti wọn yan lati ran an lọwọ lo wa gba ipo.
Ojo ireti nla kọkọ rọ fun awọn ololufẹ Chelsea nigba ti ọkan lara awọn ọjẹ wẹwẹ ti wọn gbe goke agba si ikọ naa, Mount kọkọ gba goolu wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju meje lẹyin aṣiṣe ti Ndidi, agbabọọlu Naijiria to n gba bọọlu jẹun ni Leicester city ṣe.
Amọṣa, Ndidi tun ọmọluwabi rẹ ṣe nigba to fi ori gbe bọọlu sinu awọn Chelsea ni iṣẹju kẹtadinlaadọrin ifẹsẹwọnsẹ naa.
Pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, goolu meje ni o ti wọ inu awọn Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn ti gba bayii laarin ọsẹ kan si ara wọn












