Premiership league: Liverpool fẹ́rẹ̀ ẹ́ forígbá níwájú Southampton ṣùgbọ́n orí kó o yọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ṣi n tẹsiwaju ninu fifi agbara wọn han awọn ikọ agbabọọlu yooku pẹlu bi wọn ṣe na ikọ Southampton pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan mọle.
Eyi ni ifẹsẹwọnsẹ meji ti Liverpool yoo maa bori laarin ọjs mẹrin si arawọn lẹyin to fagba han Chelsea lati gba ife ẹyẹ Super cup ni ọjọru.
Mane lo kọkọ gba bọọlu wọn awọn Southampton to jẹ iks to ti n gba bọọlu jẹun tẹlẹ ki Firmino to fọba lee nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mọkanlelaadọrin.
Amọṣa, Danny Ings ti oun pẹlu naa ti gba bọọlu ri fun ikọ Liverpool da ẹyọkan pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa de iṣẹju kẹtalelọgọrin.
Liverpool ni o di ipo keji mu ni saa liigi to kọja yoo si maa lepa ati gba liigi naa lọdun yii lẹyin to ti gba ife ẹyẹ Champions league ni saa bọọlu to kọja.








