FIFA ban: Siasia ní kò sí ìgbà tí òun àti FIFA kò ní pàdé ní kóòtù

Oríṣun àwòrán, others
Siasia, olukọni bọọlu ọmọ Naijiria ti ajọ FIFA paṣẹ fun pe eegun rẹ ko gbọdọ ṣẹ mọ lagbo ere bọọlu lagbaye titi lahun sita pe oun afaims ki oun ati ajọ FIFA maa pade ni ile ẹjọ nitori ẹsun gbigba riba.
Siasia gba ẹnu awọn aṣoju ati amofin rẹ sọrọ nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Abuja.
Bi o tilẹ jẹ pe Siasia wa nibi ipade akọroyin naa sibẹ ko ba awọn akọroyin sọrọ funrarẹ pẹlu awawi pe awọn amofin oun ti n wo ọrọ naa.
O ni oun ṣi wa ninu ikaya soke lori ti iya oun ti wọn ji gbe ti wọn ni ki oun ls maa wa ẹgbẹlẹgbẹ owo wa ki ajọ FIFA to tun gbe tiwọn de.
Ni ọjọ Ẹti ni ajọ FIFA kede pe awọn ti gbẹsẹ le kikopa Sisasia ninu ohunkohun to nii ṣe pẹlu ere bọọlu lagbaye nitori ẹsun gbigbimọ lati gba owo riba ti wọn fi kan an.
Amọṣa, Siasia ti ṣalaye pe oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun naa atipe ko si igba kankan ti ajọ naa pe oun joko lati beere ọrọ lori ẹsun naa ki wọn to gbe idajọ wọn kalẹ.
O wa sọ ọ di mimọ nibi ipade naa pe awọn amofin oun ti n gbe igbesẹ lori ohun ti yoo kan lori ọrs naa.








