Premier league: Arsenal kọrin 'kọ́stọ́mà daada ni' fún Burnley pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọkan

Arsenal koju Burnley

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lacazette, Aubameyang, Ceballos ati Pepe tan yòò bí oòrùn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà

Nnkan gbe nnkan hanu loni ni papa iṣire Emirates tii ṣe ibuba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Arsenal ati ikọ Burnley ni wọn jijọ gbe ina woju ara wọn.

Nigba ti ere gbogbo yoo fi pari, Arsenal lo gbogo ọjọ naa lọwọ

Pẹlu bi ifẹsẹwọnsẹ yii ṣe pari yii, ikọ Arsenal ti sọ Burnley di kọstọma daadaa ni

Arsenal lo kọkọ gba bọọlu wọ inu awọn nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹtala. Lacazette, atamatase ikọ Arsenal lo gba goolu naa wọle.

Arsenal koju Burnley

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin eyi, Arọni Arsenal ko simi rirọjo bọọlu lọ si oju ile Burnley bi o tilẹ jẹ pe Burnley pẹlu ko sun asunpiye, awọn naa ja fitafita ti wọn si da goolu akskọ pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelogoji.

Ọkan lara awọn atamatase to ti sọ awọn Arsenal di kọstọma daadaa, Ashley Barnes lo gba bọọlu naa wọle.

Ki wọn to lọ sinmi fun saa akọkọ Arsenal gba goolu miran wọle ṣugbọn oludari ere naa, wọgi lee lẹyin ti ẹrọ VAR ṣe afihan rẹ pe aṣiṣe waye ṣaaju goolu naa.

Eyi ni igba kọkanla ni ṣisẹ-n-tẹle ti Arsenal yoo maa ṣina iya fun Burnley lati oṣu kẹta ọdun 2009.

Oṣu kejila ọdun 2008 ni Burnley fi ẹyin Arsenal gbolẹ kanyin