Community Shield: Man City fọ́ Liverpool lẹ́nu bẹ̀rẹ̀ sáà bọ́ọ̀lù tuntun ní Wembley

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajura wa lọ tijankandi kọ o! Manchester City ṣina iya fun Liverpool lati gba ife ẹyẹ community Shield ni papa iṣere Wembley.
Man City naa lo gba ife ẹyẹ Premier League Liverpool lọwọ ni saa bọọlu to lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Raheem Sterling lo kọkọ gbayo wọ le fu Man City ṣugbọn Joel Matip sayo naa pada, lo ba di ọmi alayo kọọkan.
- Mahrez dá Super Eagles dùbúlẹ̀ lórí pápá oko tútù
- Pípè fún ìfẹ̀hónú hàn túmọ̀ sí ìdìtẹ̀ gbàjọba àti ìgbésùnmọ̀mí - Ọlọ́pàá
- Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò dágbére fáyé lẹ́yìn ìjà rẹ
- Èmi kò gbé pọ̀ pẹ̀lú Kollington Ayinla àmọ́ ọjà t'ọ́mọ ti wọ̀ lọ̀rọ̀ àwa méjééjì - Salawa Abẹni
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àsìkò tó láti fi ìwọ́de gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi àti oko ẹrú - Sowore
Wo mi ki n gba siọ ti wọn n pe ni pẹnariti ni wọn yanju rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Pep Team
Manchester City lo papa jawe olubori lẹyin ti wọn gba pẹnariti wọ le ti Liverpool si le da mẹrin pada.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City àti Liverpool ṣíde sáà bọ́ọ̀lù tuntun
Saa bọọlu tuntun bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, Manchester City ti wọn gba ife ẹyẹ Premier League ni saa to lọ yoo ṣide saa tuntun pẹlu Liverpool tawọn gba ife ẹyẹ UEFA Champions League.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Man City tun gba ife ẹyẹ FA, bẹẹ ni wọn ti Carabao Cup, awọn kan tiẹ sọ pe ife mẹrin ni wọn gba lẹyin ti wọn ṣina iya fun Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield ti saa bọọlu to lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Man City gba ife ẹyẹ Premier League pẹlu ami ayo mejidinlọgọrun un nigba ti Liverpool tẹle wọn pẹlu ami ayo mẹtadinlọgọrun.
Asiko tun ti to lati bẹrẹ iwọ o ju mi, emi o ju ọ lẹẹkan si, aago mẹta ọsan ọjọ Aiku ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo bẹrẹ ni papa iṣere Wembley niluu London.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Aṣole fun Manchester City Ederson ati agbabọọlu aaringbungbun Fernandinho ko ni le kopa ninu ere bọọlu naa, nitori o pẹ diẹ ki wọn to pada de lẹyin ti wọn ṣoju Brazil ninu idije Copa America, Claudio Bravo Bravo ni yoo dile mu fun Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa, Sadio Mane ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield nitori oun naa ṣẹṣẹ de lati idije AFCON 2019 nibi ti orilẹede rẹ, Senegal fidi rẹmi ninu aṣekagba idije naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Igba akọkọ re e ti Liverpool yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield lati ọdun 2006 nigba ti na Chelsea pẹlu ami ayo meji sẹyọkan.
Eyi ni igba kejila ti Man City yoo kopa ninu Community Shield, wọn si ti gba ife naa lẹẹmarun un .